Ọmọ ọdún méjì ni mí nígbà tí ìyà mí gbé mi sílẹ̀ - Bimbo Ademoye

Gbajugbaja oṣere tiata ti sọrọ sita lori ibaṣepọ rẹ pẹlu iya to bi lọmọ, ẹni to ni o gbe oun silẹ nigba to wa ni ọmọ ọdun meji.

Ademoye sọ eleyi ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Hauwa Magaji ni ibaṣepọ oun pẹlu iya ko kuna to gẹgẹ bi ti iya si ọmọ.

O tẹsiwaju pe otitọ nipe oun ko sumọ iya oun sugbọn oun n ṣe ojuse oun gẹgẹ bi ọmọ si iya fun iya oun.

“Iya mi wa laye, Ile rẹ ko jina si ile mi. Ko kan si ibaṣepọ laarin wa ni.

“N ko fẹ sọrọ nipa rẹ nitori mo jẹ eeyn ti ko ki n sọrọ pupọ.

“Iya mi gbe silẹ nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun meji.”

'Bi iya mi ṣe gbe mi kalẹ ni ọmọ ọdun meji jẹ ijakunlẹ akọkọ ti mo ri laye mi'

Ademoye salaye pe oun ati iya oun gbinyanju lati mu ibaṣepọ naa danọran sugbọn ko bọ si ati pe ijakunlẹ akọkọ ti oun kọkọ gba laye oun wa lati ọdọ iya rẹ.

“Ko si ibaṣepọ nla laarin awa mejeeji nitori n ko ni anfani lati mọ iya mi sugbọn mo gbiyanju lati ni ibaṣepọ pẹlu iya mi.

“Ni bayii, mo n ṣe ojuṣe mi gẹgẹ bi ọmọ si iya. Mo n ṣe owo ile ati awọn owo miiran.

“Bi ọrọ ṣe wa niyen. Mo faramọ bi nnkan ṣe wa bayi ati pe aye ko si silẹ fun ọrẹ sise ti yoo ṣe akoba fun ilera ọpọlọ mi.

“Iya mi wa laye ati o rẹ wa gan. Mo mu awọ bi mọ ṣe pipa lara Babami, ti mo si mu sisanra lara iya mi.”