You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìkẹ́dùn alága ẹgbẹ́ náà l’Ondo, Fatai Adams, tó d’olóògbé
Ẹgbẹ oṣelu PDP ẹka ti ipinlẹ Ondo ti kede ọjọ mẹta fun ikẹdun alaga ẹgbẹ naa l'Ondo, Fatai Adams to di oloogbe.
Ẹgbẹ naa ṣapejuwe iku Ọgbẹni Adams gẹgẹ bi eyi to ya gbogbo ọmọ ẹgbẹ lẹnu.
Aarọ Ọjọru ni Ọgbẹni Adams jade laye lẹyin aisan ranpẹ gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ sẹ fidi rẹ mulẹ.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lati ọwọ alukoro ẹgbẹ naa, Kennedy Peretei, ẹgbẹ ṣalaye PDP ṣalaye awọn kede ọjọ mẹta lati ṣe idaro Ọgbẹni Adams lati bu iyin fun ẹni 're to lọ.
PDP sọ ninu atẹjade naa pe ''iku alaga PDP l'Ondo lasiko ba wa lọkan jẹ pupọ.
Eyi gan an lo jẹ ki igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ ni ipinlẹ Ondo kede ọjọ mẹta fun idaro rẹ.
Ni gbogbo olu ileeṣẹ ẹgbẹ wa kaakiri ipinlẹ Ondo ni a ti fa asia walẹ lati daro Ọgbẹni Adams.
Ọdun 2020 ni Adams wọle ibo gẹgẹ gi alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ondo.
Ṣaaju igba naa ni o ti jẹ ọmọ ẹgbẹ ile igbimọ ipinlẹ Ondo laarin ọdun 2007 si 2011.
Bakan naa ni o ti ṣe igbakeji alaga ẹgbẹ osẹlu PDP ri.
Ẹgbẹ wa kẹdun pẹlu ẹbi oloogbe ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP patapata ni ipinlẹ Ondo.
A gbadura wi pe ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.''