Ọlọ́pàá ṣàfihàn afurasí alábàágbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin fásítì Ondo tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn ko ni pẹ ẹ gbe afurasi arakunrin kan Oluodun Sanni lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o ṣeku pa akẹgbẹ rẹ akẹkọọbinrin Ifoluwa Adekenle.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, arakunrin naa to jẹ akẹkọọ onipele Kaarun ni ẹka imọ Geology ni Fasiti Adekunle Ajasin, Akungba Akoko mọ nipa iku akẹkọọbinrin ti ẹka imọ ọrọ aje fasiti kanna.

Ni nkan bi ọsẹ meji sẹyin ni wọn ṣadede ba arabinrin Ifeoluwa Akande ninu agbara ẹjẹ ni ile rẹ to n gbe to wa lẹgbẹ ile ẹkọ naa.

Ohun taa ri gbọ ni pe afurasi yi gun arabinrin naa lọbẹ pa to si ji foonu Iphone rẹ gbe salọ.

Lati igba naa ni awọn ọlọpaa ti n tọ pinpin ẹni to mọ nipa iku arabinrin yii.

Ọlọpaa ṣafihan afurasi nipasẹ imọ ẹrọ tẹkinọlọji

Lọjọ Iṣẹgun ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣafihan afurasi yi ni ileeṣẹ wọn to wa ni ilu Akure.

Kmisana ọlọpaa Abayomi Oladipo sọ pe afurasi naa ji foonu arabinrin yi gbe lẹyin to gun lọbẹ pa.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye,imọ ẹrọ igbalode lawọn lo lati fi ṣawari arakunrin naa nipa titọ pinpin foonu to si ja si pe ọwọ afurasi ẹni ọdun mọkanlelogun yi lawọn ti ṣawari rẹ.

O sọ pe ''ọkan lara awọn aṣoyọri taa ṣe nibi iwadii yi ni pe a fi imọ ẹrọ igbalode ṣawari afurasi to lọwọ ninu iku arabinrin akẹkọọ fasiti AAUA.Lọjọ Keji oṣu Keji ọdun 2024 ni wọn gbe ẹjọ wa si agọ ọlọpaa wipe wọn ba arabinrin akẹkọọ fasiti naa ẹni ogun ọdun ninu agbara ẹjẹ ni ile to n gbe lẹba ilẹ ẹkọ naa''

O tẹsiwaju pe ''wọn gbiyanju lati gbe lọ si ile iwosan fasiti naa nibi ti wọn ti ni ki wọn gbe lọ si ile iwosan akọṣẹmọṣẹ to wa ni Ikare Akoko.Nibẹ ni wọn ti sọ pe arabinrin naa ti dagbere faye.''

“Lasiko iwadii wa la ri wi pe foonu ologbe di awati.Nipa lilo imọ ẹrọ tẹkinọlọji igbalode, a tọ pinpin foonu naa ti a si ri wi pe ọwọ arakunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan Olubodun Sanni ti o jẹ alabagbe arabinrin to ku yi ni foonu naa wa''

O fikun pe awọn ko ni pẹ lati wọ arakunrin naa lọ si iwa ileẹjọ ni kete tawọn ba pari gbogbo iwadii to yẹ.