Ọlọ́run Ọba nìkan ló le yí mi lọ́kàn padà pé kí ń juwọ́ lẹ̀ - Biden

Aworan Aarẹ Joe Biden ati Geroge Stephanopoulos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Amẹrika Joe Biden ti sọ pe Ọlọrun Ọba nikan lo yi oun lọkan pada lati dupo iwọle pada gẹgẹ Aarẹ Amẹrika.

O sọ eyi nigba to n ba ikọ iroyin ABC sọrọ nipa ipo ti ilera rẹ wa, eyi to n ba ọpọ lẹru.

Biden ti wa fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe alaafia ni oun wa, ti oun setan lati tun se saa mii gẹgẹ bii Aarẹ.

“Mo n se ayẹwo lorekore. Ni ojojumọ ni mo ma se ayẹwo,” O sọ fun Geroge Stephanopoulos.

Aarẹ Biden, ẹni ọdun mọkanlelọgọrin, wogile ero awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic ti wọn ni ko yẹra kuro ninu idije naa fun eeyan to kere lọjọ ori lati dije lẹyin to lulẹ ni takunọrọ pẹlu Donald Trump lọsẹ to kọja.

"N ko ro pe ẹnikẹni koju oṣuwọn lati di Aarẹ tabi bori eto idibo yii, ayafi emi.” Biden ni ohun to waye lọsẹ to kọja ko sẹyin rirẹ to rẹ ati otutu to wa lasiko naa.

Aarẹ dahun awọn ibeere ti wọn bi lasiko ifọrọwerọ naa daradara ju igba to o n sọrọ pẹlu Donald Trump lọ, bo ti lẹ je pe ohun rẹ walẹ.

“Idahun mi ree. Mo maa kopa ninu eto idibo yii, mo ma bori lẹkan sii,” Biden sọ fun awọn alatilẹyin rẹ.

O ni oun ri gbogbo nnkan ti awọn n kọ nipa oun pe oun ti dagba lati dije sugbọn oun gbagbọ pe oun ko dagba lati mu aye dẹrun fun araalu Amẹrika.

“Mo ri gbogbo iroyin ti wọn sọ pe mo ti da rugbo.

“N jẹ mo darugbo nigba ti mo pese iṣẹ milọnu mẹdogun?

“N jẹ mo darugbo nigba ti mo wọgile gbese awọn akẹkọọ milọnu marun un ọmọ Amẹrika?

“N jẹ ẹ ro pe mo dagba ju lati fi idi Donald Trump janlẹ?”

Gbogbo awọn alatilẹyin rẹ pariwo soke pe “Rara”