Mọ̀ nípa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà tó wọlé nínú ètò ìdìbò UK

Aworan ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà tó wọlé nínú ètò ìdìbò UK

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES/ BAYO ALABA.COM/ TAIWO OWATOMI-INSTAGRAM

Ẹgbẹ oṣelu Labour Party lo bori ọpọ ipo ninu eto idibo to waye ni ilẹ UK lọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2024.

Aṣeyọri yii lo fopin si ọdun mẹrinla ti ẹgbẹ oṣelu Conservative ti wa ni ijọba.

Lara awọn oludije to jawe olubori ni awọn eeyan kan to jẹ pe orisun wọn ni orilẹede Naijiria.

Ninu ọgbọn oludije, mẹfa laarin wọn ri ipo dimu ni ẹkun idibo wọn.

Eeyan mẹjọ ti wọn jẹ apapọ ọmọ Ilẹ Gẹẹsi ati Naijiria lo jade dupo fun ẹkun idibo wọn ti mẹrin si bori eto idibo naa fun ẹgbẹ oṣelu Labour.

Ẹgbẹ oṣelu Conservative naa ni ọmọ Naijiria mẹrin fun eto idibo sugbọn meji ninu wọn ni wọn wọle idibo.

Ohun to yẹ ko mọ nipa awọn MP to ni orisun Naijiria.

Bayo Alaba

Wọn bi Bayo Alaba ni Forest Gate ni ila oorun London.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaba jẹ olori Board Trustee fun Phoenix Recource Centre, ileeṣẹ nla kan to wa ni ilẹ UK ati Oke okun.

MP Bayo Alaba lo bori ẹkun idibo rẹ ni Newcastle labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour .

Onisowo yii ni apapọ idibo to jẹ 15,395 lati fi bori akẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ oṣelu Conversative, Gavin Haran, ẹni ti apapọ ibo rẹ jẹ 11,368.

Kemi Badenoch

Wọn bi arabinrin Badenoch ni ọjọ keji oṣu kinni ọdun 1980 ni Wimbledon ni London.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ mẹta ti awọn obi rẹ ti wọn jẹ ọmọ Naijiria, Femi ati Feyi Adegoke bi.

Kemi Badenock lo igba kekere rẹ niluu Eko lorilẹede ati ni orilẹede Amẹrika nibi ti iya rẹ ti n siṣẹ olukọ gẹgẹ bii ọjọgbọn

Oun naa di ipo rẹ mu gẹgẹ bi aṣoju ẹkun idibo Ariwa iwọ oorun Essex.

Ẹgbẹ oṣelu Conversative ko fi bẹ bori eto idibo.

Badenoch jẹ akọwe funm ẹka to n risi isowo ati idokowo lasiko ti saa Rishi Sunak.

O ni apapọ ibo to jẹ 19,360.

Lati ọdun 2017 ni Kemi Badenoch ti jẹ MP fun Saffron Walden

Tawio Owatemi

Wọn bi Taiwo Owatemi ni ọjọ kejilelogun oṣu kee ọdun 1992.

Iya rẹ jẹ nọọsi lo tọ pẹlu awọn ẹgbọn rẹ ọkunrin lẹyin ti baba rẹ papoda nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹfa.

Ọdun 2019 ni Owatemi kọkọ di MP ni ile igbimọ aṣofin UK.

O jẹ ọkan lara aṣofin to wa lati ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Bakan naa lo kawe gba oye Master ninu imọ ogun lilo lati fasiti Kent ni ilẹ UK.

O ni apapọ ibo to jẹ 19,696 lati fi bori alatako rẹ Tom Mercer to ni apapọ ibo 8,522.

Chi Onwurah

Wọn bi Chinyelu Susan “Chi” Omwurah ni ọjọ kejila o’su kẹrin ọdun 1965 ni Wallsend.

O lọ si ile ẹkọ Kenton ni Newcastle , to si gba iwe ẹri ni imọ Electrical Engineering lati Imperial College niluu London.

Ọdun 2010 ni Chi ti n kọdọ ipo ijọba mu labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Labour.

O ni apapọ ibo to jẹ 18, 875 lati fi bori eto idibo ọjọ kẹrin oṣu keje.

Florence Dauta Eshalomi

Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹsan an ni ọdun 1980 ni wọn bi Florence.

O kawe gboye ninu imọ oṣelu ati ajọsepọ agbaye lati fasiti Middlesex.

Oun ni ẹni akọkọ ti yoo lọ fasiti ninu idile rẹ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ Labour.

O ni apapọ ibo to jẹ 21,528 lati fi bori eto idibo ọdun 2024.