You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó sàn fún mi kí n jẹ́ ọmọ Naijiria ju ọmọ orílẹ̀èdè olómìnira Oodua Republic lọ - Obasanjo
Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ni o san pe ki oun jẹ ọmọ bibi orilẹede Naijiria ju ki oun jẹ ọmọ Oodua Republic.
Obasanjọ sọrọ yii lasiko ti wọn bi nipa awọn eeyan to n pe fun idasilẹ Oodua Republic nigba to n gba alejo awọn ẹgbẹ ariwa kan ti gomina Kano tẹlẹri, Malam Ibrahim Shekarau lewaju fun niluu Abeokuta.
O ni eto iṣejọba ẹlẹkunjẹkun to waye lorilẹede Naijiria ṣaaju gbigba ominira rẹ lọdun 1960 ni ipilẹṣe aisi iṣọkan ati aigbọraẹniye gbogbo to n waye lorilẹede Naijiria bayii.
Obasanjo ni o se koko ni ijọba gbe awọn igbesẹ to yẹ nipa mimọ agbegbe ti yoo pese olori ni awọn ẹka ijọba.
“Asiko ti to lati bẹrẹ si ni sisẹ papọ lori ilọsiwaju Naijiria, Bẹẹni, e pe ara yin ni ẹgbẹ ariwa sugbọn emi n pe yin ni ẹgbẹ Naijiria nitori ibi ti ẹ ti wa ko yẹ ko jẹ iṣoro.
“Nibi ti wọn ti bi mi ko yẹ ko tako mi pe ọmọ jẹ Naijiria. O san mi ki n jẹ ọmọ Naijiria ju pe ki n pe ara mi ni ọmọ Oodua Republic.
“Iwuri nla lo jẹ pe mo jẹ ọmọ Ypruba, ṣugbọn o n ko le tako Naijiria nitori mo jẹ Yoruba. A ni lati wa eeyan gidi lati sisẹ yii. A ko fẹ mọ ibi ti o ti wa. A ni lati sisẹ papọ.
“A ti ja ara wa kunlẹ, a ti ja irin eeyan dudu kunlẹ, Afrika ati gbogbo agbaye ni apapọ, A ni lati fi gbogbo eyin sẹyin, ki a sisẹ papọ fun igbega Naijiria.”
Lori ipo ti orilẹede Naijiria wa bayii, Obasanjo ni gbogbo iṣoro naa ni yoo di ohun igbagbe ti gbogbo ọmọ Naijiria ba le fọwọsowọpọ lati sọ ara wọn di ọkan.