You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Níbo ni Bobrisky ń lọ tí ọwọ́ iléeṣẹ́ Immigration ilẹ̀ Nàìjíríà fi tẹ̀ ẹ́ lẹ́nu ibodè Sẹ̀mẹ̀?
Awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iwọle-wọde arinrinajo lorilẹede yii (Immigration) ti mu Idris Okuneye (Bobrisky), ni ẹnu ibode Seme, lasiko ti ọkunrin to maa n ṣe bii obinrin naa fẹẹ sa kuro ni Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti ajọ Nigeria Immigration Service(NIS), fi sita lalẹ ọjọ Aje ana, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii ni wọn ti sọ eyi di mimọ.
Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe wi, wọn ni awọn ti n fi ọrọ wa Bobrisky lẹnu wo.
Agbẹnusọ kan ninu ajọ naa, DCI KT Udo, ṣalaye pe, ‘’a ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo, a si maa fa a le awọn ẹka to yẹ lọwọ fun itẹsiwaju.
“A fi n da araalu loju pe a ko ni i yẹsẹ lori ojuṣe wa nipa ẹnu ibode ti iṣẹ wa da le lori.’’
Kí ló mú Bobrisky fẹ́ẹ́ sá kúrò ní Naijiria?
Iroyin ọlọkan-o-jọkan lo n jade nipa Bobrisky latigba ti ile ẹjọ ti dajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun un.
Akọkọ ni ẹwọn rẹ naa ti wọn ni ko ṣe rara, bẹẹ ni awuyewuye tun jade pe inu ile adagbe kan ni Bobrisky wa, to n ṣe faaji rẹ fun oṣu mẹfa gbako.
Fọn-an-ran ohùn ti wọn tun ni ti Bobrisky ni, eyi to n kede pe oun san miliọnu mẹẹeẹdogun naira koun maa ba ṣẹwọn, naa tun jẹ idi kan ti ọkan Okuneye Idris ko fi balẹ rara.
Ninu fidio kan ti Bobrisky funra rẹ fi sori ayelujara lo ti n bẹ awọn eeyan, pe ki wọn fi oun lọrun silẹ.
O ni ṣe oun nikan ni gbajumọ (celebrity) to wa ni Naijiria ni, to fi jẹ pe ọrọ gbogbo ki i se lori alabahun oun.
Bakan naa ni àbọ̀ iwadii igbimọ ti Minisitra fun ọrọ abẹle, Olubunmi-Tunji Ojo gbe kalẹ, fi han pe Bobrisky ni anfaani si tẹlifiṣan ati awọn eeyan to n ran niṣe lọgba ẹwon to wa.
Wọn lo jẹ anfaani ounjẹ to wu u, o si tun ri ẹrọ firiiji lo ninu ẹwọn rẹ.
Gbogbo eyi ni awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu Idris ati ijọba paapaa.
Eyi ni a gbọ pe o ṣee ṣe ko ka Bobrisky laya soke, ko si fẹẹ wa ọna ti yoo fi yẹra ni Naijria fun igba diẹ na.
Ṣaa, iwadii ṣi n lọ lori ọrọ ọkunrin to n mura bii obinrin naa.