You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tí Amẹrika dá owó ìrànwọ́ USAID sílẹ̀ òkèèrè dúró - àwọn wo ló pàdánù jùlọ?
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, BBC News Yoruba
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Loṣu Kinni ọdun yii lẹyin ọjọ mẹta ti ifilọlẹ ijọba Aarẹ Donald Trump waye ni awọn ọkunrin kan ṣadeedee yọju si ọfiisi ajọ USAID ti Amẹrika fi ṣe n iranwọ fun lajọlajọ nilẹ okeere.
Awọn ọkunrin naa lawọn n ṣiṣẹ fun ajọ Doge to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba Amẹrika eyi ti gbajugbaja oniṣowo Elon jẹ adari wọn.
Ohun ti wọn beere nileeṣẹ USAID to wa ni Washington ni bi wọn ṣe le ṣiṣẹ lori ẹrọ kọmputa ajọ naa.
Ẹwẹ, Trump ti gbẹsẹ le owo iranwọ silẹ okeere kete ti wọn bura fun un tan gẹgẹ bii aarẹ Amẹrika fun saa keji.
Owo to to $63bn ni Amẹrika na lọdun 2024 gẹgẹ bii owo iranwọ silẹ okeere.
Ijọba Amẹrika ko tii sọ pato nnkan to fẹ ṣe lori ọrọ naa, amọ, BBC ti sẹwadii lori lori awọn ti igbesẹ Aarẹ Trump lori owo iranwọ silẹ okeere yoo pa lara julọ.
Oṣiṣẹ ajọ USAID kan sọ fun BBC pe ibẹru bojo ti gbalẹ lati igba tawọn oṣiṣẹ ajọ Doge ti bẹrẹ si ni wa si ọfiisi USAID.
O ni awọn ọdọkunrin naa wa lati ileeṣẹ Musk ni wi pe ọkan lara wọn sọ foun pe oun ti ṣiṣẹ fun SpaceX ri.
Oṣiṣẹ USAID ṣalaye pe awọn to wa lati Doge naa ṣe iwadii lori kọmputa awọn akanṣe iṣẹ kan to da lori ọrọ oju ọjọ, nnkan amuṣagbara, ibadọgba, ọrọ akọ ati abo, wọn si bẹrẹ si ni pa gbogbo ẹ rẹ.
Awọn kan sọ fun wọn pe lara awọn akanṣẹ iṣẹ naa yoo fun eeyan bii miliọnu meji lounjẹ ni Sudan, amọ, ẹti ikun ni wọn si wọn.
Ọsẹ meji lẹyin asiko yii ni Trump kede pe ijọba yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iranwọ ounjẹ fawọn eeyan ni Sudan ki alaafia le jọba.
Amọ, oṣiṣẹ USAID ni awọn ọkunrin to wa lati Doge tun pa eyi naa rẹ lori kọmputa.
Oṣiṣẹ ijọba Amẹrika kan sọ fun BBC pe ijọba fagile eto iranwọ ounjẹ lawọn agbegbe kan ni Sudan tori o tako eto ijọba nilẹ okeere, amọ, iranwọ naa ko duro ni ọpọ agbegbe ni Sudan.
Oṣiṣẹ USAID sọ pe akọwe ijọba Amẹrika lo n sọ awọn eto ti ijọba n da duro.
Nigba to di aarin oṣu kẹta, ijọba ti tu USAID ka, mẹẹdogun loku ninu awọn oṣiṣẹ bii ẹgbẹrun un mẹwaa to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ naa.
Trump fi orukọ awọn eto iranwọ ti o da duru ranṣẹ si ile aṣofin, o ni ida 83% awọn eto ti USAID n nawo le lori loun ti dinku.
Eyi tumọ si pe ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ti padanu iṣẹ wọn lojiji kaakiri agbaye.
Sumayya Muhammad Bala to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ti USAID n ṣe iranwọ owo lapa ariwa Naijiria ni awọn o lero pe ijọba Amẹrika le gbe igbesẹ ti won gbe lojiji.
Sumayya n kọminu lori awọn ọmọde atawọn iya wọn ti wọn maa n ri iranwọ ounjẹ gba nipasẹ iranwọ ajọ USAID.
O ni awọn eeyan yii ko lagbara lati lọ tọju ara wọn nile iwosan.
Lọjọ kẹwaa osu Kẹrin yii ni BBC ri aṣiri iroyin kan pe adinku ida 56% ti i ṣe $21.5bn ni yoo ba owo iranwọ ti Amẹrika n ṣe silẹ okeere.
Eto ilera alaboyun atawọn ọmọ ikoko
Ko ni si owo iranwọ fawọn alaboyun atawọn ọmọde mọ, $1.3bn ni Amẹrika na lori ẹka yii nikan lọdun 2024.
Apa ilẹ olooru Afirika ni ọpọ owo yii lọ tori nibẹ ni ida 70% awọn alaboyun to ku lọdun 2023 ti wa.
Dokita Muhammad Abdullahi to ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ kan ti USAID n ṣe iranwọ fun lati ṣatilẹyin fun ile iwosan mejila ni igberiko sọ pe ominu n kọ oun lati igba ti Trump ti da iranwọ naa duro loṣu Keji ọdun yii.
O ni kinni yoo ṣẹlẹ si obinrin to nilo lati lọ sile iwosan lai si iranwọ mọ? Dokita naa ni iru ẹni bẹẹ le gba ibẹ ku.
Ayman Abdelmohsen to jẹ oṣiṣẹ ajọ UNFPA ṣalaye pe ọpọ orilẹede lo n janfaani iranwọ lati ọdọ USAID fawọn alaboyun ati awọn ọmọde.
Abdelmohsen ni asiko ti to fawọn orilẹede lati maa pese itọju to peye fawọn araalu, ki wọn si gbẹkẹ le iranwọ lati ilẹ okeere mọ.
O ni kii kan ṣe wi pe Amẹrika fopin si iranwọ silẹ okeere nikan, bi ko ṣe bi ijọba Trump ti kede igbesẹ naa lojiji.
USAID ni lo n pin oniruur oogun lagbaaye lọdọọdun eyi to na ajọ naa ni $600m lọdu.
Gbogbo eyi ni adinku nla yoo ba bayii.
Amẹrika ti na $12bn lori eto ilera agbaye papaa julọ lori ikọ fere, arun iba ati arun HIV, ki Trump to kede idaduro iranwọ.
Ikọ fere
Ikọ fere lo to n pa eeyan to le ni miliọnu kan lọdun lo n gba owo to kere julọ.
Dokita Lucica Ditiu to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ UN lori wiwa ojutuu si ikọ fere sọ pe ọpọ eeyan lo ro pe ko si ikọ fere mọ.
Ikọ fere wa lara awọn arun ti ijọba Amẹrika fi ranṣẹ si ile aṣofin pe wọn yoo da iranwọ duro fun.
Choub Sok Chamreun ṣe agbatẹru ọkan lara awọn akanṣẹ iṣẹ lẹka eto ilera lagbaaye ti Amẹrika ti da iranwọ duro fun bayii.
$3m ni ajọ USAID fi ṣe iranwọ fun gbigbogun ti ikọ fere ni Cambodia.
Ni ipari oṣu Kinni ọdun yii, Ọgbẹni Chamreun gba aṣẹ lati da iṣẹ duro nipari oṣu keji.
Oun naa ni lati da awọn oṣiṣẹ rẹ bii igba duro lẹnu iṣẹ.
Chamreun ni ''a ti n ṣiṣẹ lati ri pe ko si ikọ fere mọ ni Cambodia titi ọdun 2023, amọ, mi o mọ nnkan to maa ṣẹlẹ bayii.
Ajọ ti Dokita Lucica n ṣagbatẹru rẹ si n ri iranwọ gba lati ọdọ ijọba Amẹrika, ṣugbọn ko le sọ igba ti iranwọ naa yoo dopin.
O ni nnkan to buru ni bii gbogbo agbaye ṣe gbẹkẹle Amẹrika nikan fun iranwọ lati dẹkun bi ikọ fere ti n ran.
Arun HIV/Aids
Ijọba orilẹede Amẹrika ti na owo to to $5bn lati gbogun ti arun HIV/AIDS ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin nipasẹ eto kan lati ọfiisi aarẹ ti wọn pe ni Pepfar.
Iwe iroyin New York Times sọ pe oṣiṣẹ 270,000 kaakiri agbaye to n ṣiṣẹ lori ati dẹkun bi arun HIV ṣe n ran ni wọn sọ fun pe ki wọn ma wa sibi iṣẹ mọ.
Akọsilẹ fi han pe miliọnu kan eeyan ati abọ miliọnu awọn ọmọde ni yoo ti lugbadi arun naa titi 2030 ti Amẹrika ba le da eto iranwọ nipasẹ Pepfar duro.
Arun iba
Owo to to $1bn ni Amẹrika n na lọdọọdun lati gbogun ti arun iba lagbaaye.
Fun apẹẹrẹ, awọn ile iwosan ti wọn ti n tọju arun iba lo ti di titi pa.
Amẹrika ti da iranwọ fun itọju arun iba naa duro lorilẹede DR Congo.
Amẹrika tun n na $2bn lọdọọdun lati gbogun ti ikọ fere, arun iba ati HIV.
Amọ, ikede ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin fidi rẹ mulẹ pe ko ni si iranwọ owo mọ fun itọju awọn arun mii yatọ si HIV, arun iba ati ikọ fere.
Eyi tumọ si pe ko ni si iranwọ owo mọ fun itọju arun Mpox ni DR Congo, tabi Ebola ni Uganda.
Ikede ijọba Amẹrika loṣu Kẹrin tun ṣalaye pe adinku ida 55% yoo ba iranwọ fun iṣẹlẹ pajawiri.
Eto ti ijọba fi ko ounjẹ ranṣẹ lati Amẹrika si ilẹ okeere naa yoo dopin.
Trump ti sọ ṣaaju pe iranwọ nipasẹ ajọ USAID ko wa ni ibamu pẹlu eto ijọba Amẹrika lori ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn orilẹede ilẹ okeere.
Ijọba ni eto iranwọ silẹ okeere ti yoo ba tẹsiwaju gbọdọ wa ni ibamu pẹlu nnkan ti ijọba Amẹrika be fẹ.
Fun ọpọlọpọ ọdun lawọn eeyan kan ti n sọ pe ijọba Amẹrika n na anadanu owo silẹ okeere.
Amọ, ọpọ awọn eeyan yii lo gbagbọ pe diẹ diẹ ni ijọba ni lati fopin si awọn iranwọ yii ki o ma baa mu ipalara to pọ wa.