Kí ló ń fa àríyànjíyàn lẹ́yìn tí APC borí ìbò ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ 18 ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn oludije ẹgbẹ Oṣelu APC lo bori ibo si ipo alaga kansu gbogbo to wa ni ipinlẹ Ondo lasiko eto idibo ijọba ibilẹ to waye kaakiri agbegbe ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni ipinlẹ naa lọjọ Satide.

Alaga ajọ eleto idibo Ipinlẹ Ondo, ODIEC, Joseph Aremo to kede esi idibo naa n'ilu Akurẹ ṣalaye pe yatọ si ipo alaga kansu, awọn oludije ẹgbẹ oṣelu APC kan naa lo wọle si gbogbo ijoko kansilọ mẹtalelugba to wa ni ipinlẹ naa.

Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ondo naa fi kun un pe gbogbo awọn alaga ti wọn dibo yan ni wọn yoo gba iwe ẹri moyege lọjọ Aje, tí awọn Kansilọ yoo si gba ti wọn ni ọjọ Isegun.

Awọn ẹgbẹ Oṣelu to kopa ninu eto idibo naa ni, Action Alliance (AA), African Democratic Party (ADP), Action People's Party (APP), All Progressives Congress (APC), All Progressives Grand Alliance (APGA), Boot Party (BP), Labour Party (LP), New Nigeria People's Party (NNPP), National Rescue Movement (NRM), Social Democratic Party (SDP), Youth Party (YP), ati Zenith Labour Party (ZLP).

Kíni ẹgbẹ́ PDP sọ nípa ètò ìdìbò náà?

Ẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo tọka si eto idibo si ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ondo naa gẹgẹ bi ere ọmọde lasan, eyi to tako ofin ati ilana eto idibo.

Adari eto iroyin ati ipolongo lẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Lẹyẹ Igbagbọ sọ pe awọn mọ pe ajọ eleto idibo ipinlẹ ọhun ko kun oju oṣuwọn lati dari eto idibo naa, idi rẹ niyi ti wọn ko fi kopa.

O tun salaye siwaju sii pe ẹgbẹ oṣelu PDP wulẹ ti mọ ibi ti ọrọ eto idibo naa yoo ja si, nitori iwadi wọn ti fidi rẹ mulẹ saaju pe Ajọ ODIEC yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ APC atawọn oludije rẹ.

Ki lawọn adari ẹgbẹ oṣelu APC sọ ni tiwọn?

Gomina Ipinlẹ Ondo Lucky Orimisan Aiyedatiwa ti gboriyin fun ajọ ODIEC fun aseyọri eto idibo ijọba ibilẹ l'ondo.

Aiyedatiwa kete lẹyin to dibo rẹ ni wọọdu 4, Ugbo Nla nijọba ibilẹ Ilajẹ, sọ pe eto idibo naa lọ laisi wahala kan, ti ODIEC si seto idibo naa ni ibamu pẹlu ofin.

O gboriyin fun awọn ara ilu plẹlu bi wọn ṣe kopa ninu eto idibo naa.

Ninu ọrọ rẹ, igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo Olayide Adelami sọ pe inu ohun dun bi awọn eniyan se jáde lati kopa ninu eto naa.

Ninu atejade latọwọ Akọwe eto iroyin Gomina (ni ofisi igbakeji Gomina) John Akinduro, wọn sọ pe eto idibo yi yoo samuduro ijọba tiwantiwa, ti yoo si jẹ ki awọn ara ilu ni imọlara ijọba lawọn ẹsẹ kuku.

Igbakeji Gomina gboriyin fun ODIEC fun aseyọri eto idibo naa.

Oludije sipo Alaga nijọba ibilẹ Gusu Akure Olugbenga Fasua sọ pe eto idibo naa jẹ eto idibo ijọba ibilẹ akọkọ nipinlẹ Ondo ti ko ni wahala kan ninu.

O gboriyin fun ODIEC fun isẹ takuntakun ti wọn se, saaju eto idibo ati lẹyin eto idibo naa.