Ìfẹ̀họ́núhàn tí bẹ̀rẹ̀ sí ní rọlẹ̀ ní France lẹ́yìn ọjọ́ márùn ún

Ifẹhọnuhan ti bẹrẹ si ni rọlẹ ni orilẹede France lẹyin ọjọ marun un ti awọn eniyan bẹrẹ si ni binu tako bi ọlọpaa ṣe yinbọn pa ọdọkunrin kan nibẹ.

Arakunrin Nahel M ni ọlọpaa yinbọn pa lasiko ti ọlọpaa da duro ti ko si duro.

O kere tan eniyan 150 ti ọlọpaa tun fi panpẹ mu ni Ọjọ Isinmi, ti wọn si fi panpẹ mu eniyan 700 ni alẹ Ọjọ Satide.

Ọpọlọpọ eniyan lo ti n kesi awọn afẹhọnuhan lati dẹkun rẹ, to fi mọ awọn mọlẹbi Nahel.

Awọn Mayor kaakiri orilẹede Faranse ni wọn ti kesi awọn araalu lati ṣe ifẹhọnuhan tako ifẹhọnuhan naa ati bi awọn eniyan se n sẹkọlu si ile itaja.

Ni ilu Nantere to jẹ ilu Nahel ni gomina ibẹ, Patrick Jarry ti ni inu oun dun si bi ifẹhọnuhan naa rọlẹ.

Amọ o ni awọn eniyan ko gbọdọ gbagbe ohun to fa ifẹhọnuhan naa ati ipe fun idajọ otitọ.

Mayor ilu Reims sọ fun awọn araalu to pejọ lọgọọrọ pe awọn ko ni ifẹhọnuhan to jasi ikọlu laaye lorilẹede Faranse.

Bakan naa ni wọn ni awọn ti n pariwo fun ọpọlọpọ ọdun lori bi iṣejọba wọn ṣe da nkan miran ti ko buyii fun awujọ.

Awọn afẹhọnuhan naa ba ọpọlọpọ ile, ọkọ jẹ lasiko iwọde wọn naa fun ọjọ marun un.

Saaju ni awọn to n sewode naa ti sekọlu si ile Mayor ilu Paris, tí wọ́n sì tún yìbọn ba ìyàwó àti àtàwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń sálọ.

Ìwà yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń bu ẹnu àtẹ́ lù tí wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn tó ṣe iṣẹ́ náà.

Olóòtú ìjọba France, Elisabeth Borne júwe ìgbésẹ̀ náà bí èyí tìkò tọ̀nà àmọ́ wọn kò rí ẹnìkankan mú láti fẹ̀sùn pé ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí.

Ijọba orilẹ-ede France tun kede pe oun yoo da ẹgbẹrun lọna ogoji ọlọpaa si gbogbo orilẹ-ede naa ni alẹ Ọjọbọ.

Eyi ko sẹ yi ifẹhọnuhan to n waye nibẹ lẹyin ti ọlọpaa sekupa ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan.

Minisita fun ọrọ abẹnu lo sọ bẹẹ lẹyin ipade pẹlu Aarẹ Emmanuel Macron.

Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn ni wọn da awọn ọlọpaa ẹgbẹrun mẹsan an sita amọ ijọba ko tii kede ilu ko fararọ.