Ìyàwó tuntun Olori Temitope Ogunwusi ti wọ Ààfin o! Ẹ fójú l'óúnjẹ́

Wọn ti dajọ ọjọ naa pe, wọn da igba, igba si ti ko, Olori Temitope ti wọ Aafin Ooni Adeyeye Ogunwusi bayii gẹgẹ bi aya.

Gbogbo eto idan ni ilana aṣa ati iṣe Yoruba waye ni agbegbe Magodo ni ipinlẹ Eko nibi ti awọn obi iyawo wa.

Ẹ wo lara awọn aworan bi eto igbeyawo naa ṣe lọ.

Lọwọ yii, Kabiyesi Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji ni a le pe ni ọbalaye ti gbogbo eeyan n sọ lọwọ bayii.

Lati ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an to ti fẹ olori Mariam Anako, ọba ọọni ti di ọba ti wọn n sọ ni igboro Aye.

Laarin oṣu kan ni Kabiyesi Ọọni fi fẹ olori mẹrin lẹyin Olori Mariam.

Nibayii, Olori ikẹfa yoo tun wọ inu aafin ile Oodua l’ọjọ Aje ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa.

Orukọ olori tuntun yii ni Ọmọọbabinrin Temitọpẹ Adeṣẹgun.

Agbẹnusọ fun Aafin Ooni Ife naa fi sita pe yoo ṣẹlẹ.

Ta ni Temitọpẹ Adeṣẹgun to fẹ di olori tuntun l'Aafin Ọọniriṣa?

Aworan atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Ọọni Ile Ifẹ, Otunba Ọlafare fihan pe Ọmọọba ilu Ijẹbu ni Temitọpẹ Adeṣẹgun .

Gbajumọ to ti ṣiṣẹ lẹka ijọba ati ti aladani ni. Bakan naa lo n ri si akoso awọn ajọ ẹlẹyi ju aanu kan pẹlu.

Lasiko iṣejọba Amofinagba Babatunde Fashola gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko, Ọmọọbabinrin Temitọpẹ Adeṣẹgun la gbọ pe o ṣe amugbalẹgbẹ fun Ọmọọbabinrin Adenrele Adeniran- Ogunsanya to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ ọhun nigba naa.

Ṣaaju lo ti kọkọ kawe gba iwe ẹri imọ ijinlẹ diploma ninu imọ ede Linguistics ati atupalẹ imọ iwadi data processing ni fasiti ilu Eko lọdin 1998 ati 2000 ki o to tun gba ìmọ ijinlẹ ninu akoso okoowo, Business Administration ni fasiti Eko kan naa.

Bakan naa lo tun ni iriri lẹka iroyin nitori oun ni atọkun eto ipolongokan ti ileeṣẹ eto ilera nijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lori afẹfẹ ti wọn pe akori rẹ ni “Health-Wise” lọdun diẹ sẹyin.

Akẹkọọ jade ọpọ ileẹkọ giga fasiti bii Fasiti ilu Oxford, United Kingdom; INSEAD Business SSchoo ni Fontainebleau, France; Fasiti Cambridge, Judge Business School, United Kingdom; ati Harvard Kennedy School of Government lorilẹede Amẹrika ni Temitọpẹ Adeṣẹgun.

Laipẹ yii loun ati Ọọni Ogunwusi da iṣẹ pọ lati ṣe idasilẹ ajọ eleyinju aanu kan ti wọn pe ni ‘Hope Alive’ lati maa pese awon ohun amayedẹrun fawọn igberiko.