You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Tẹ́ẹ bá mọ Adebutu dáadáa, ó máa ń ṣe èèyàn bí ẹni tí kò jẹ́ pàtàkì"; "Irọ́ ńlá lẹ pa" - Igun Adebutu àti Jimi Lawal
Bo ṣe n lọ ninu gbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Ogun kii ṣe keremi rara, bi igun kan ṣe ni awọn ni ade kan naa ni igun mii ni oludije awọn lo wọle lati du ipo gomina.
Kẹrẹkẹrẹ, idibo kuku ti n sunmọ amọ a ṣi n ri awọn ẹgbẹ oṣelu kan ti aarin wọn ko tii gunmọ depo depo ki ẹnu wọn ko lori taa ni yoo dije.
BBC Yoruba kan si ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun lati mọ taa gan lo fẹ gbe opo ẹgbẹ ro ninu idibo ọdun to n bọ, ọtọọtọ la ba lẹnu wọn.
"Tẹ́ẹ bá mọ Adebutu dáadáa, wọ́n máa ń ṣe èèyàn bí ẹni tí kò jẹ́ pàtàkì". Ọkan lara wọn, Jimi Lawal ní torí pé Adebutu jẹ́ ọmọ bàbá olówó ló ṣe ń ṣe àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bí àwọn tí kò pàtàkì.
“Joshua ni ọpọlọpọ maa n pe mi nigba ti mo darapọ mọ PDP Ogun torii bi Alhaji Adebutu ṣe maa n ṣe gbogbo eeyan”.
Bakan naa, a tun ba Ọgbẹni Solari to jẹ akọwe ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Ogun sọrọ to si ṣalaye idi ti o ṣi fi jẹ pe Adebutu ni oludije loju ti awọn naa.