You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ gba owó oṣù kẹtàlá, ẹ má dá àwọn alátakò lóhùn– Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede pe ki awọn osisẹ ipinlẹ naa lo fi ọkan wọn balẹ nitori oun yoo san owo osu kẹtala fun wọn gẹgẹ bi o ṣe maa ṣe lọdọdun.
Gomina sọ eleyi ni bi ayẹyẹ ‘Christmas Carol’ to waye nile ijọba ni Agodi niluu Ibadan, o ni ki osu kejila to pari ni oun ri pe awọn osisẹ gba owo oṣu wọn.
O wa rọ awọn osisẹ lati yago fun oniruuru ete ti awọn ẹgbẹ alatako gbe kiri lati ba eto iṣejọba rẹ jẹ.
Wọn ni si san owo ọsu ko ki n ṣe aṣeyori sugbọn maa san owo osu kẹtala
Gomina tẹsiwaju pe gbogbo ọna awọn alatako oun ṣe ba iṣejọba oun jẹ pe oun ko ni aṣeyori kankan sugbọn ko ni da oun duro lati san owo oṣu awọn osisẹ ko to di ipari ọdun
O ni awọn osisẹ ipinlẹ Oyo yoo ni anfani lati gba owo kẹtala miiran nitori ijọba oun ko kọ iyan wọn kere rara
“Ẹ maa dawọn lohun, a mọ pe wọn yoo sọ pe bii mo ṣe fun owo oṣu kẹtala lọdọdun ko ki n ṣe aṣeyori sugbọn mo tun sọ fun pe, ki oṣu to pari, ẹ gba owo oṣu naa.
“Owo oṣu kejila ati kẹtala ni a san fun un awọn osisẹ wa lati fi ṣe ọdun keresimesi ati ayẹyẹ ọdun tuntun.
"T awọn ẹgbẹ alatako ba nnkan miiran to da ju nnkan ti a ti ṣe nipinlẹ Oyo, ki wọn bọ sita lati sọ fun awọn araalu ”