You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò sí owó nínú iṣẹ́ tíátà, mi ò sì ní bàbá ìsàlẹ̀ – Opeyemi Ayeola
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Opeyemi Ayeola ti ní òun kìí kọjá àyè òun tí òun kìí sì ṣe ju ara òun lọ nítorí iṣẹ́ tíátà tí òun yàn láàyò kì í pawó wọlé tó bẹ́ẹ̀ jùlọ fún òun.
Opeyemi Ayeola nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Instagram rẹ̀ níbi tó ti ń dúpẹ́ fún Ọlọ́run lórí àwọn nǹkan tó kójọ nínú ọdún yìí ṣàlàyé àwọn ìlàkàkà rẹ̀ láti ìgbà tó ti ń bá eré tíátà bọ̀.
Ó ní ìpárí ọdún 2021 ni òun tó ra ilẹ̀ kan ní ìlú Ibadan láti ọdún tí òun ti bẹ̀rẹ̀ eré tíátà àmọ́ inú òun dùn báyìí nítorí òun ti kúrò ní onílẹ̀ kan di oní àìmọye.
Ó ṣàlàyé pé òun kò ní bàbá ìsàlẹ̀ tàbí màmá ìsàlẹ̀ lágbo iṣẹ́ yíátà nítorí náà ni òun ṣe mọ ìwọ̀n ara òun tí òun kì í sì ṣe ju ara òun lọ.
Gbájúmọ́ òṣèré náà tún tẹ̀síwájú pé òun kì í bá wọn kópa nínú gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ tí àwọn akẹgbẹ́ òun máa ń ṣe.
Ayeola fi kun pé òun kò jẹ́ kí gbogbo àwọn afẹfẹyẹ̀yẹ̀ tí àwọn akẹgbẹ́ òun máa ń ṣe lórí ayélujára wọ òun lójú nítorí òun kìí ṣe ẹni tó máa ń ní dandan àfi kí òun tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn.
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé tí òun bá tẹ ipá mọ́ iṣẹ́ ọwọ́ òun dáradára òun gbogbo yóò bọ̀ sípò fún òun.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ́ kárakára, níní àfojúsùn pẹ̀lú àtìlẹyìn Ọlọ́run, òun gbàgbọ́ pé òun gbogbo yóò di ìrọ̀rùn.
Bákan náà ló fi kun pé òun gbàgbọ́ pé kò ì tíì pẹ́ jù láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.