Wọn ò rí oṣù tuntun lónìí, Saudi Arabia kéde Ọjọ́rú ọ̀tunla gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ọdún ìtúnu ààwẹ̀

Ijọba orilẹede Saudi Arabia ti kede Ọjọru ọtunla gẹgẹ bi ọjọ ọdun ituna aawẹ Ramadan ọdun 2024.

Ikede yii waye lẹyin ti wọn ko le ri oṣu tuntun lọjọ Aje ni Saudi.

Eleyii tumọ si pe aawẹ yoo tan lọla ọjọ Iṣẹgun eyi ti yoo jẹ ọgbọnjọ ti aawẹ naa bẹrẹ, nigba ti ọdun yoo si waye ni Ọjọru.

‘’Wọn ko ri oṣu tuntun ni Saudi Arabia lọjọ Aje, eyi to tumọ si pe Ọjọru ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 2024 ni ọdun itunu aawẹ yoo jẹ bayii,’’ iwe iroyin Haramain News lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.

Ẹwẹ, Sultan ilu Sokoto, Alhaji Muhammad Saad Abubakar, to jẹ aarẹ ajọ NSCIA to n ri si ọrọ awọn ẹlẹsin islam ti kepe awọn musulumi wi pe ki wọn maa wo oju ọrun fun oṣu tuntun.