You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkọ mi kò le fàyè gba gbogbo ìrégbè tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí ká ló wà láyé - Maryam Abacha
Iyawo olori ìjọba ológun ni Naijiria nigba kan, Hajiya Maryam Abacha, ti sọ pe akọni, ati ọlọgbọn adari ti ko jẹ́ ki aini akiyesi ba nnkan jẹ́ ninu iṣejọba rẹ ni ọkọ oun.
Ààrẹ ológun naa dari Naijiria laarin ọdun 1993 si 1998, lẹyin rogbodiyan oṣelu to waye nitori ọ̀rọ̀ June 12.
Maryam Abacha sọ pe ọkọ oun gbiyanju lati mu ki ifọkanbalẹ wà ni Naijiria, to si tun mu ki alaafia jọba, tako bi nǹkan ṣe ri lasiko yii.
O ni ahesọ ọrọ lasan ni àwọn nnkan buruku ti wọn n sọ nipa oloogbe Sani Abacha, nitori pe ko si iwa ijẹkujẹ ati ibajẹ ninu iṣejọba lasiko rẹ̀.
Oriṣiriṣi awọn ẹ̀sùn kiko owo ìlú jẹ, ati lilo àṣẹ onikumọ ni awọn eeyan fi kan ijọba Abacha.
Ṣugbọn Maryam Abacha sọ pe iwa awọn ìjọba asiko yii buru púpọ̀ ju ti asiko naa lọ.
Ìgbé ayé olóògbé Sani Abacha
Ogunjọ, oṣu Kẹsàn-án, ọdun 1943 ni wọn bi Sani Abacha n'ilu Kano.
O lọ si ile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ati girama n'ilu Kano.
Lẹyin naa lo lọ si ile ẹkọ awọn ológun n'ilu Kaduna lọdun 1962 si 1963 ko to o lọ si ile ẹ̀kọ́ ológun Aldershot Military Training College ni England lọdun 1963.
Bakan naa lo tun kẹ́kọ̀ọ́ ni Warminster National Military Training College ni UK lọdun 1966.
Ni 1971, o kẹ́kọ̀ọ́ ni Jaji Military College niluu Kaduna.
Lẹyin naa lo tun kẹ́kọ̀ọ́ ni Kuru College of Policy and Management niluu Jo's, lọdun 1981.
O tun kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ nipa eto aabo ni orile-ede Canada ati America lọdun 1982.
Ojiji ni iku Sani Abacha ba gbogbo ọmọ Naijiria, paapa nitori pe ko ṣe àìsàn kankan ko to kú lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfà, ọdun 1998.
Iyawo rẹ, Maryam Abacha sọ pe igbe aye ọkọ oun gẹgẹ bi ológun, yàtọ̀ si igbeaye to gbe pẹlu ẹbí rẹ̀.
O ni oloogbe fẹ́ràn lati ma a ṣeré ati àwàdà pẹlu ẹbi rẹ, ti kii si fi adura ṣeré rara.