You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ṣetán láti ran ECOWAS lọ́wọ́ láti yanjú aáwọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ – AU
Ajọ African Union, AU, ni inu oun bajẹ lẹyin igbesẹ orilẹ-ede Mali, Burkina Faso ati Niger lati fi ajọ ECOWAS Silẹ.
Opin ọsẹ to kọja ni awọn orilẹ-ede mẹtẹta ọhun ti wọn ko jina sira wọn fi ikede naa sita.
Ninu atẹjade kan ti adari AU, Moussa Faki Mahamat fi lede, o ni AU ti ṣetan lati ṣatilẹyin fun ECOWAS fun ijiroro lọna ati pari aawọ to wa nilẹ laarin rẹ awọn ọmọ ẹgbẹ.
O ni irẹpọ to dan mọran lo yẹ ko wa laarin awọn orilẹ-ede nilẹ Afrika, kii ṣe pe ki wọn maa tuka.
Mahamat ke si awọn adari ECOWAS lati ni ipade alaafia pẹlu awọn olori awọn orilẹ-ede mẹtẹta naa, ati pe oun ti ṣetan lati pese gbogbo atilẹyin to yẹ fun wọn.
Ọrọ yii lo n jade lati ọdọ AU lẹyin ti ijọba Naijiria bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn orilẹ-ede mẹta naa ṣaaju.
Aarẹ Naijiria, to tun jẹ alaga ECOWAS, Bola Tinubu sọ pe ko tọ ki awọn adari ti araalu ko dibo yan maa fi ẹtọ araalu lati yan olori ti wọn n fẹ ati lati ṣowo bo ṣe wu wọn dun wọn.
Nigba ti wọn n kede ipinnu wọn lati fi ECOWAS silẹ lọjọ Aiku, Niger, Mali, ati Burkina Faso ninu atẹjade kan ti wọn jọ buwọlu ni ECOWAS n dun mọhurumọhuru mọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.
Ologun to ditẹgbajọba ni Mali sọ pe oun ti yan igbimọ ti yoo bojuto bi orilẹ-ede naa yoo ṣe fi ECOWAS silẹ, ti ko si sohun ti yoo ti yoo ṣẹlẹ si awọn.
O ni igbesẹ naa ko ni ni atubọtan kankan lara orilẹ-ede ọhun.
Amọ ṣa, Mali ṣi wa ninu ẹgbẹ West African Economic and Monetary Union (Waemu), eyii to jẹ ẹgbẹ ọmọ ilẹ adulawọ ti wọn ti n sọ ede French, ti wọn si n na owo CFA.