You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N kò ní fi nǹkankan sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láti jogún - Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun ko ni fi ogun kankan silẹ fun ẹnikẹni lati jogun ati pe ohun ti o jẹ oun logun ju ni ẹko fun awọn ọmọ oun.
Buhari so eleyi nigba ti o ṣe abẹwo ikini ku ọdun si Emir ti ilu Daura, Dr Faruk Umar Faruk ni aafin rẹ.
Nigba ti Aarẹ sọrọ, o rọ awọn obi ati alagbato lati ṣe itọju awọn ọmọ wọn, ki wọn si fi ibẹru ọlọrun si ọkan wọn, ibọwọ fun awọn agba ati igbe aye ti o ni itumọ lati le fun wọn ni eto ékó to yanranti.
“Awọn ọmọ mi ti mọ pe n ko ní fi nnkankan silẹ fun ẹnikẹni lati jogun. Ohun to jẹ mi logun ju ni lati rii pe awọn ọmọ mi ri eto ẹkọ to peye.”
“Afojusun mi ni lati rii pe awọn ọmọde ri iwulo wọn nibikibi ti wọn ba ti ba ara wọn.
Aarẹ Buhari ni oun ti sọ fun awọn ọmọ oun, pataki julọ awọn ọmọbinrin rẹ pe wọn gbọgbọ kawe jade fasiti ki wọn to ṣe igbeyawo.
Aarẹ tun wa pe fun pe ki wọn maa kọ awọn ọmọde ni itan nitori ti awọn ọmọde o ba mọ ibi ti wọn ti wa, o ni yio nira fun wọn lati ṣe ojuṣe wọn ni ona to tọ.