You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Ọmọ tí wọn kò bá sin ibi rẹ̀ dáadáa, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ si rèé...'
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Broadcast Journalist
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni ariwo ayọ̀ sọ nílé Tunde Ijanusi àti ìyàwó rẹ̀, Joy John nígbà tí wọ́n bí ọmọ tuntun jòjòló.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yìí fẹ́ rò pọ̀ mọ́ ìbánújẹ́ nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn alábọ́dé tí ìjọba tó wà ní ìlú Emure-ile, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo kọ̀ láti gbé ibi ọmọ fún wọn.
Gẹ́gẹ́ bí àṣà Yorùbá láti bo ibi ọmọ mọ́lẹ̀ nígbà tí ọmọ bá dáyé tán, Tunde lọ bá àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tó gbẹ̀bí ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun gbé ibi ọmọ òun àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà ní wí pé àwọn kò rí ibi mọ́.
Wọ́n ní àwọn ní ìgbàgbọ́ pé ajá ló jẹ ibi ọmọ náà níbi tí àwọn gbé e sí, tí èyí sì mú kí bàbá àti ìyá ọmọ tuntun jòjòló yìí fi igbe bọnu láti mọ ibi tí ibi ọmọ wọn sọlẹ̀ sí.
Joy John, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún, ní àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ọ́hún tilẹ̀ sọ fún òun pé tí òun b’gbà kí àwọn ṣe ọ̀rọ̀ náà ní òkú òru, àwọn kò ní gba owó ìtọ̀jú lọ́wọ́ àwọn.
Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá báyìí níbi tí àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́ta ti ń káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́.
Èyí ló mú kí BBC News Yorùbá mú oókan kún eéjì láti tọ àwọn àgbàlagbà lọ láti sọ pàtàkì ibi tó máa ń jáde lẹ́yìn ọmọ.
Nígbà tí a kàn sí Araba ìlú Osogbo, Ifayemi Elebuibon, bàbá ṣàlàyé pé ibi ọmọ ṣe pàtàkì sí ìgbé ayé ọmọ tó ń tẹ̀lẹ́ bọ̀ wá sáyé.
Elebuibon ní káàkiri orílẹ̀ ayé, nígbà tí ibi ọmọ bá tó jáde ni wọ́n máa ń kí ènìyàn kú ewu ọmọ àti pé ohun ló fà á tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé tibi tire jọ máa ń rìn pọ̀ ni.
“Nígbà tí ibi ọmọ bá tó jáde ni ọkàn máa ń balẹ̀ pé obìnrin bímọ.”
Bàbá Elebuibon nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpínlẹ̀ Ondo náà ní ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ṣe kò dára tó nítorí ó yẹ kí wọ́n ṣe àmójútó ibi ọmọ náà dáradára ni.
“Ibi ọmọ jẹ́ ohun tí ènìyàn gbọdọ̀ mójútó dáadáa, kí wọ́n tọ́jú ẹ̀, kò yẹ kí wọ́n jẹ́ kí ajá ó gbé e.”
“Ní ọjọ́ tí a bá rí ibi ni ibi ń wọlẹ̀, ó yẹ kí wọ́n lọ sin ibi náà síwájú balùwẹ̀ tàbí ẹnu ọ̀nà ilé ìyá rẹ̀ ni.”
“Ó ṣe pàtàkì púpọ̀ nílẹ̀ Yorùbá láti sin ibi ọmọ lẹ́yìn tí obìnrin bá bímọ, kòdá ibi ọmọ ni wọ́n máa ń sín ifá sí láti dènà àbíkú láyé àtíjọ́.”
Ọmọ tí wọn kò bá sin ibi rẹ̀ dáadáa sábà máa ń kojú ìṣòro tó pọ̀ nílé ayé
Araba ìlú Osogbo náà fi kun pé gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́ ọmọ, ara ibi tó gbé wá sílé ayé ló wà nítorí ó jẹ́ ohun tí ènìyàn máa ń tọ́jú dáadáa.
Ó ṣàlàyé pé tí ajá bá gbé ibi ọmọ, ó ní àwọn ìpalára tó máa ń mú bá ọmọ náà lọ́jọ́ iwájú.
“Ọmọ tí wọn kò bá sin ìbi rẹ̀ dáadáa, ìgbésì ayé rẹ̀ kìí dọ́gba, ẹni tí wọ́n bá sin ibi rẹ̀ dáadáa, ìwọ̀nba ni wàhálà rẹ̀ yóò mọ láyé.”
“Tí wàhálà tí ènìyàn bá ń kojú bá pọ̀jù, ìbéèrè tó máa ń jáde lẹ́nu àwọn àgbàlagbà ni pé ṣé wọn ò sin ibi ọmọ náà dáadáa ni?”
“Ó ṣeéṣe kí ibi ọmọ tí wọn kò rí yìí padà fa làásìgbò sí igbé ayé ọmọ náà ní ọjọ́ iwájú.”
Ìṣe àti àṣà wa kò jọ tí òyìnbó, ìgbé ayé wa kò le papọ̀
Nígbà tó ń fèsì lórí ìgbàgbọ́ àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó tí wọ́n ní nǹkan tí ènìyàn máa ń sọnù ni ibi ọmọ, Bàbá Elebuibon ní ìgbé ayé àwa Adúláwọ̀ àtàwọn òyìnbó kò jọra wọn rárá.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn òyìnbó ló ń gbé ìgbé ayé làásìgbò nítorí ọwọ́ tí wọ́n fi mú àwọn nǹkankan.
Bákan náà ni bàbá ní àwọn ènìyàn ilẹ̀ òkèrè mìíràn náà ní àṣà ti wọn tí wọn kìí fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.
“Báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíràn ni, ó yẹ ká pa òfin àti àṣà wa mọ́ kí ilé ayé lè ọrùn fún wa.”
“Tí a ò bá ti ṣe àwọn nǹkan bó ṣe yẹ ká ṣe é, kò lè rí bó ṣe yẹ kó rí.”
Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ nọ́ọ̀sì, òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn méjì l'Ondo f'ẹ́sùn jíjí olubi ọmọ tuntun
“Wọn ni ki n ma fi ọrọ naa ṣe ariwo rara nitori aja lo gbe ibi ọmọ naa nibi ti wọn tọju e si.”
Iya ati baba ọmọ ti wọn n wa olubi rẹ ti sọ nnkan ti oju wọn ri lasiko ti wọn n beere fun ibi ọmọ naa lọwọ awọn nọọsi to wa lẹnu iṣẹ.
Baba ọmọ ni ṣe ni wọn bẹrẹ si ni bẹ oun nigba ti wọn lọ wo ibi ti wọn gbe ibi ọmọ si ti wọn ko rii nibẹ.
Awọn oṣiṣẹ mẹta ni ile-iwosan alabọde to jẹ ti ijọba ni ilu Emure n'ijọba ibilẹ Owo, nipinlẹ Ondo ni awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu fun bi wọn ko ṣe le pese ibi ọmọ kan ti wọn bi si ile iwosan naa.
Rolake Adeyemi to jẹ nọọsi, Rukayat Afusipe to jẹ amugbalẹgbẹ rẹ ati obirin kan to jẹ ẹṣọ alaabo nile iwosan naa ni wọn ko si gbaga ọlọpaa lẹyin ti wọn kuna lati pese ibi ọmọ tuntun ti wọn gbẹbi rẹ nile iwosan ọhun.
Baba ọmọ to jẹ ọdọmọkunrin, Tunde Ijanusi, ẹni ọdun mẹtalelogun, ni iyawo rẹ, Joy John, ọmọ ọdun mọkandinlogun, bi ọmọ obinrin kan ni ile iwosan naa ni Ọjọbọ, ọjọ kẹẹdogun oṣu yii.
Amọ nigba ti baba ni ki oun lọ ri ibi ọmọ mọlẹ gẹgẹ bo ṣe maa n ri nilẹ Yoruba, wọn ko ri i gbe fun baba ọmọ tuntun naa.
Awọn mọlẹbi Tunde lo pariwo sita nigba ti wọn gbọ pe awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa ko lee pese ibi ọmọ tuntun ọhun fun baba rẹ.
Gẹgẹ bi baba ọmọ naa ṣe wi o ni: “nigba ti mo beere fun nọọsi to gbẹbi ọmọ mi ko wa fun mi ni ibi ọmọ naa, ẹnikan to n ba wọn fọ'ṣọ ni ki n wa wo ibi ti wọn tọju ẹ si.
“Bi a ṣe de ibẹ, mi o ri nkankan. Obirin naa waalọ pe awọn to ku wa pe ko si ibi ọmọ nibi ti wọn tọju ẹ si.
“Nigba ti nọọsi naa ati awọn to ku de, wọn ni ki n ma binu, ki n jẹ ka bo ọrọ naa mọlẹ.
“Wọn ni ki n ma fi ọrọ naa ṣe ariwo rara nitori aja lo gbe ibi ọmọ naa nibi ti wọn tọju e si.”
Iya ọmọ naa fi kun ọrọ ọkọ rẹ pe awọn nọọsi naa tilẹ ni wọn ko ni gba owo itọju lọwọ awọn ti wọn ba gba lati ṣe ọrọ naa ni oku oru.
Joy wi pe: “ẹbẹ mi si ijọba ati gbogbo araalu ni ki wọn ba mi gba ibi ọmọ mi jade ni gbogbo ọna ti wọn ba le lo tori mi o gbọ ri pe aja wọ ile iwosan waa gbe ibi ọmọ”.
Ìwadìí n lọ lọ́wọ́ láti mọ bí ibi ọmọ ṣe rìn jáde — Ọlọ́pàá
Alukoro ajọ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya, to fi idi ọrọ naa mulẹ lakoko to n ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ wi pe ni tootọ ni awọn agbofinro ti gbọ si ọrọ naa ti wọn si ti fi ofin gbe awọn mẹta to nii ṣe pẹlu ọrọ ọun.
Odunlami-Omisanya wi pe: “awọn mẹta ti wa ni ihamọ ọlọpaa ni ‘Owo Area Command’ ti wọn n fi ọrọ wa lẹnu wo. Lara wọn ni nọọsi kan, amugbalẹgbẹ rẹ ati obirin kan to jẹ ẹṣọ alaabo ni ile iwosan naa”.
Alukoro ajọ ọlọpaa naa fi kun pe awọn yoo wadi ọrọ naa finifini lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Kò sí nọ́ọ̀sì nínú àwọn tì ọlọ́pàá mú —Àjọ àwọn nọ́ọ̀sì
Ẹwẹ, ajọ awọn nọọsi nipinlẹ Ondo ti wipe ko si ọmọ ẹgbẹ awọn kankan to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Atẹjade kan lati ọwọ alaga ẹgbẹ naa, Kehinde Olomiye, ṣalaye pe ko si akọṣẹmọṣẹ nọọsi kankan ninu awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Olomiye ni “a fẹẹ ki gbogbo aye mọ pe ko si akọṣẹmọṣẹ nọọsi kankan to lọwọ ninu iṣẹlẹ jiji ibi ọmọ gbe to waye nile iwosan alabọde to wa nilu Emure-ile nijọba ibilẹ Owo.
“awọn oṣiṣẹ eleto ilera meji ti ọlọpaa mu ati ẹṣọ alaabo to jẹ ikẹta wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wa tori pe wọn kii ṣe ojulowo nọọsi.
“A rọ ijọba ati awọn ọlọpaa lati ṣe iwadi ni kikun lati le tu iṣu de isalẹ koko ki wọn si fi oju ẹni ti aje ọrọ naa ba ṣimọ lori wina ofin.”