Kí ló dé tí àwọn èèyàn ṣe ń fi orúkọ Ibrahim Chatta gbowó lórí ayélujára?

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì Ibrahim Chatta ti rọ gbogbo àwọn tó ń lo àwòrán rẹ̀ lórí ayélujára láti máa fi tọrọ owó, pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwòrán Ibrahim Chatta tó ṣàfihàn wí pé ó ní ìjàmbá iná, tí ara rẹ̀ sì bó yánnayànna ṣe gba orí ayélujára lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Àwòrán yìí ló ṣokùnfá bí àwọn ènìyàn se ń gbé ìròyìn kiri wí pé Chatta ní ìjàmbá iná tó sì farapa gidigidi.

Wọ́n ní ìfarapa yìí mu kó nílò owó tabua láti fi tọjú ara rẹ̀ lọ́wọ́ àìlera tó ń ba fínra yìí.

Ìdí nìyí tí àwọn kan sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé àwòrán yìí sórí ayélujára, tí wọ́n sì ń pè fún ìrànlọ́wọ́ fún Chatta láti fi tọ́jú ara rẹ̀.

Kokoko lara ọta mi le - Chatta

Ẹ̀wẹ̀, nínú fọ́nrán kan tí ibileojogbon fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram rẹ̀, ni Chatta ti sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ pé kokoko lara ọta òun le.

o ni òun kò ní ìjàmbá iná kankan.

Ibrahim Chatta ní láyọ̀ àti àláfíà ni òun wà àti wí pé òun kò ní ìjàmbá ọkọ̀ tàbí iná kankan.

Bákan náà ló ní òun kò sí ní ilé ìwòsàn tàbí lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn kankan.

Chatta ní òun ṣe fọ́nrán fidio náà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀ wí pé kò sí nǹkankan tó ń bá òun fínra.

O ni àwòràn tí àwọn ènìyàn ń gbé kiri náà jẹ́ èyí tí òun fúnra lára òun gbé sí orí ẹ̀rọ Instagram òun.

Ó ní oko eré ni ayàwòrán kan, Hakeem Effects ti dárà sí òun lára pẹ̀lú àwọn ohun èlò eré láti lè jẹ́ kó dàbí òótọ́.

Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń kàn sí láti mọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ si gangan àti pé inú òun dún fún ìfẹ́ tí àwọn ènìyàn ń fi han òun.

Ẹ yé kọ́ RIP sori aworan mi, n ko ku o - Chatta

Chatta tún fi àsìkò náà jáwé ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé àwòrán náà láti fi tọrọ owó fún ìtọ́jú òun láti jáwọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ó ní àwọn mìíràn tilẹ̀ tún ń kọ ọ́ sórí ayélujára wí pé olódì òun ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

“Àwọn mìíràn ti ẹ̀ ń kọ R.I.P. sórí àwòrán mi, ẹ jọ̀ọ́ ẹ yé ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.”

Ó fi kun wí pé, kí àwọn ènìyàn dẹ́kun láti máa gbé ìròyìn tí kò fìdí múlẹ̀ nípa òun sórí ayélujára láti máa fi tan àwọn ènìyàn.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ibi ayẹyẹ ìgbáfẹ́ kan ni òun lásìkò tó ń ṣe fọ́nrán láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láya àti àláfíà ni òun wà.

Ta ni Ibrahim Chatta:

Gbajumọ osere tiata ni Ibrahim Tapa, ọmọ ilu Bacita nipinlẹ Kogi nii se, ẹya Tapa Lempe si lo jẹ.

Ọjọ Ktala osu Kẹwa ọdun 1970 ni wn bi gbajumọ osere naa, eyii tii se ọdun mejilelaadọta sẹyin.

Amọ Chatta ti pẹ nilẹ Yoruba, to si n ba wọn kopa ninu ere Yoruba lorisirisi.

Gbajumọ osere naa lo ni ẹbun pupọ nipa isẹ tiata, ko si si ipa ti ko le ko ninu sinima.

Bo ti n kopa bii ọdọ, lo lee se bii agbalagba, alakọwe, Babalawo ati janduku pẹlu.

Bakan naa ni Ibrahim Chatta ni ẹbun orin kikọ ati oriki ilẹ Yoruba pẹlu.

Lara awọn gbajumọ ere ti Chatta ti kopa ni Wehinwo, Alaaru, Police and Thief, Akirisore, Agboorun ati bẹẹ bẹẹ lọ.