Ìjì líle Cyclone Mocha kọlu Myanmar, ẹ̀mí èèyàn 32 sọnù

Cyclone Mocha

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan mejilelọgbọn lo ti jade laye bayii lẹyin iji lile Cyclone Mocha to kọlu orilẹ-ede Myanmar lọjọ Aiku.

Iji lile Cyclone Mocha naa jẹ ọkan lara iji lile to buru ju to tii kọlu orilẹ-ede naa laarin ọgọrun ọdun sẹyin.

Agbegbe ti awọn eeyan ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni Rakhine, to jẹ agbegbe ti omi pọ si.

Yatọ si awọn to ku, ogunlọgọ ile gbigbe ati ọpọ dukia lo ti ba iji lile naa lọ.

Awọn iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe iye eeyan to ku pọ ju iye awọn ti iroyin gbe lọ amọ ijọba ologun to n tukọ orilẹ-ede naa lati ọdun 2021 ko ka awọn ogunlende kan lagbegbe Rohingya.

Ni Sittwe, to jẹ olu ilu Rakhine, awọn oju opopona lo ti di pa latari awọn igi to dawo, eyii to di awọn oju ọna ọhun.

Lawọn ilu mii, iroyin ni ṣe lawọn ọmọ ogun tun n kọlu awọn araalu lẹyin iji lile naa.

Ẹgbẹgbẹrun eeyan lo ti sa kuro ni ariwa iwọ oorun Sagaing bayii lẹyin ti awọn ologun bẹrẹ si n kọlu awọn eeyan nibẹ.

Ọkan lara awọn eeyan ti ọrọ naa kan sọ fun BBC pe “Lati ọjọ kejila oṣu Karun un ni ojo ti n rọ… awọn ọmọ ogun tun n lu wa, koda a bẹru awọn ologun naa ju iji lile ọhun lọ.”

Wọn ni ko din ni ẹgbẹrun marundinlogun eeyan ti ikọlu awọn Ologun ṣe ipalara fun lagbegbe Kani ati Khin Oo.