You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn Krìstẹ́ní Yoruba Nation kọ̀wé sí CAN láti pínyà!
Ẹgbẹ Yoruba Nation Christian Association (YORNCA), awọn Kristẹni to wa laarin awọn ajijagbara fun orilẹede Yoruba yii n pe fun didaduro gedegbe ati kikuro labẹ akoso apapọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria CAN.
Eyi lo mu ki wọn kọ iwe ti wọn si dari si Aarẹ ẹgbẹ CAN, Alufa agba, Daniel Chukwudumebi Okoh, lati fi to gbogbo ẹgbẹ leti pe asiko ile ti to fun awọn ọmọm Yoruba to wa laarin CAN.
Wọn kọ sinu rẹ pe “koko iwe na ni lati sọ fun ẹgbẹ CAN pe ẹgbẹ Yoruba Nation Christian Association (YORNCA) to ko gbogbo ọmọlẹyin Kristi atawọn ile ijọsin to wa nilẹ Yoruba to darapọ mọ awọn nile ati lẹyin odi pe awọn ti fẹ kuro lara ẹgbẹ CAN.
Ohun ti eleyi tumọ si ni wipe wọn n fẹ ki awọn Kristẹni ẹya Yoruba yọra kuro labẹ idari ati akoso ẹgbẹ CAN.
Ki ni ohun ti ẹgbẹ YORNCA fẹyin ti gan ti wọn fi fẹ da duro?
Nigba ti BBC Yoruba kan si akọwe agba ẹgbẹ naa, Pasitọ E.A Agboola, o jẹ ko di mimọ pe Ọlọrun alaaye ni awọn kọkọ fẹyinti ti awọn ṣe gbe igbesẹ yii, bakan lo sọ pe ẹgbẹ apapọ Yoruba Self Determination Movement (YSDF) to jẹ asia nla ti gbogbo ẹgbẹ to n ja fun iran Yoruba wa labẹ rẹ to si ni Ọjọgbọn Banji Akintoye jẹ baba fun awọn naa.
“Baba wa Ọjọgbọn Banji Akintoye lo fi ẹgbẹ wa lọlẹ”, Agboola sọ fun BBC Yoruba.
"Iran ti kii korira tabi ṣe ẹlẹyamẹya ni Yoruba torinaa la ṣe gba awọn ẹsin ti oyinbo mu wa laye atijọ lai ja tabi ni ẹnikẹni lara lati yan eyi ti o ba fẹ ṣe."
Awọn ijọ, adari ijọ ati eekan wo lo wa ninu ẹgbẹ YORNCA?
Akọwe ẹgbẹ naa jẹ ko di mimọ pe bi ẹnikẹni ba n reti ki orukọ awọn ilumọọka Pasitọ wa lara awọn, ko lee ri bẹẹ toripe wọn ti baba wa labẹ akoso CAN amọ sibẹ sibẹ, awọn adari ijọ ti wọn si jẹ Pasitọ to to mẹrinlelogun lo jẹ alakoso ẹgbẹ YORNCA.
Agboola ṣalaye pe kii ṣe pe awọn ni nkankan lodi si ẹgbẹ CAN to wa ni Naijiria amọ bi lẹta wọn ṣe sọ, oju awọn ọmọlẹyin Kristi ti ri ọpọlọpọ idamu ninu orilẹede Naijiria ti wọn si gbagbọ pe awọn to fẹ pa ilu run lo wa nidi eyi paapaa bi wọn ṣe ni wọn n doju le ẹya Yoruba.
Bakan naa wọn tọka si bi awọn agbesunmọmi ṣe n pa awọn Kristẹni kaakiri orilẹede Naijiria ti wọn si ni awọn ni ọpọlọpọ ẹri bii ti Deborah Samuel ti wọn pa ni ọjọ Kejila Oṣu Karun ọdun 2022 ti awọn kan sọ ni okuta ti wọn si tun dana sun un ni ilu Sokoto.
Lafikun, o mẹnu ba ikọlu to waye si ijọ Katoliki ti ilu Owo lọsan gangan nipinlẹ Ondo ni ọjọ Karun Osu Kẹfa ọdun yii kan naa.
Ẹwẹ, wọn ni awọn o na ika abuku si ẹsin tabi ẹya kankan o toripe ọpọlọpọ eekan Naijiria lo jade lati bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
“Torinaa ni awa Kristẹni nile ati lẹyin odi to jẹ ọmọ Yoruba ṣe kọ lati jẹ ẹru ni ilu tiwa ti Ọlọrun fun wa. Awa ajọ Kristẹni ọmọ Yoruba yoo yapa kuro patapata lorilẹede Naijira ni kete ti wọn ba ti kede Yoruba Nation gẹgẹ bi orilẹede ara rẹ, eleyi ko si ni pẹ rara si akoko yii”.
“A fọwọ ati ẹsẹ si gbogbo akitiyan ti Baba wa ati adari, Ọjọgbọn Banji Akintoye n ṣe a si mọ pe wọn ti kọ iwe ranṣẹ ni ilana ofin si Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lati fi ifẹ iran Yoruba han lati yapa kuro lorilẹede Naijria.