2023: Atiku Yóò Fìdí Tinubu Janlẹ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Eko- Dino Melaye

Agbẹnusọ fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu People's Democratic Party, Dino Melaye ti sọrọ lori iwoye rẹ fun eto idibo to m bọ.

Melaye ti ni Atiku Abubakar yoo fidi oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu janlẹ ninu eto ìdibo aarẹ lọdun 2023.

Melaye sisọ loju ọrọ yii nigba to sọrọ lori ẹrọ mobunmaworan ni pẹlu bí ipinlẹ Osun ṣe jẹ ọkan lara ipinlẹ APC, ẹgbẹ oselu PDP sì borí nibẹ fun ìdí eyi, awọn yoo bori ni Ipinlẹ Eko.

"Ti eto idibo ba waye loni ni Ipinlẹ Eko, ẹgbẹ oselu PDP yoo bori, Atiku o fidi Tinubu janlẹ."

Atiku wa ni Ipinlẹ Eko ni ọjọ mẹta sẹyin, a ri bi awọn eeyan ipinlẹ Eko ṣe tẹ wọgba.

Awọn eeyan fẹ ki Atiku di aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria."

Melaye tẹsiwaju pe bi awuyewuye ṣe n waye ninu ẹgbẹ oselu PDP ni ko jẹ ohun tuntun nítori pe gbogbo ẹgbẹ oselu loni awuyewuye ti wọn dojukọ, ti wọn si ti n gbiyanju lati yanju rẹ.

"Ko si awuyewuye ninu ẹgbẹ oselu PDP, PDP jẹ ẹgbẹ oselu ti mimi kan o le mi, bi bo ṣe bayin sọrọ yii, ko si nkankan.

"Ìpolongo yoo bẹrẹ ni ipari osu to n bọ, a ni osu kan kí ìpolongo to de, mo fi da yín loju pe gbogbo awọ ni yoo ni iyanju.

"N ko sọ ko si awuyewuye ninu ẹgbẹ oselu PDP sugbọn ko da aseyọri ẹgbẹ oselu PDP duro."