Pius Adesanmi: Òní ló pé ọdún márùn ún ti oníṣiti àgbà ònkọ̀wé dágbére fáyé

Aworan ọjọgbọn Pius Adesanmi

Oríṣun àwòrán, Pius Adesanmi

Ọjọ naa ree bi ana ti iroyin gba oju opo ayelujara pe Ọjọgbọn Pius Adesanmi papoda.

Ọpọ lo n ṣe eemọ wi pe ko jẹ jẹbẹ.

‘’Ha! Ki lo ṣe e? O ṣe aarẹ ni abi ki lo le mu ẹmi ẹni to kun fun alaafia bayii lọ?’’

Ṣugbọn iku ko da ọjọ bẹẹ ni aarun ko da oṣu.

Ti asiko onikaluku ba si ti to, o di dandan ko pari irinajo rẹ.

Lọjọ Kẹwaa oṣu Kẹta ọdun 2019 si ni Ọjọgbọn agba onkowe nii Pius Adesanmi dagbere faye pe o di gbere.

Ohun ati awọn arinrinajo mii lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu Boeing 737 X8 ileeṣẹ Ethiopia Airlines to ja lulẹ.

Baalu naa n gbera lati Ethiopia lọ si Nairobi ko to ja lulẹ.

Lọjọ ti Ọjọgbọn Adesanmi jade laye, o fi aworan kan soju opo rẹ ni Facebook to si fi ẹsẹ ọrọ Bibeeli lati inu iwe orin Psalm jẹri si pe ọwọ Olorun lo n dari oun.

Ọpọ lo ri Pius Adesanmi gẹgẹ bi akọni,oniwaasu, onwoye awujọ ati onigege ara.

Ilu Isanlu ni wọn ti bi Pius Adesanmi to si nifẹ si ede ati aṣa rẹ.

Botilẹ jẹ wi pe ọpọ ọrọ to n kọ ti awn eeyan si mọ si n waye lede Gẹẹsi, ko fi igba kankan gbagbe orisun rẹ ti akawe lorisi a si maa jẹyọ ninu ede Yoruba lara ọrọ to n gbe safẹfẹ.

Pius Adesanmi a maa ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi olukọ botilẹ jẹ wi pe ọrọ rẹ a maa dabi ti awọn oniwaasu litireṣọ to ṣaaju bi tiẹ.

Gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀jọ̀gbọ́n Adesanmi pẹlu BBC Yoruba sàlàyé pé, oloogbe naa jẹ ẹni ti a n pe ni olùfẹ ọmọ ènìyàn, ẹni to fẹ́ràn ará ìlú ti kìí fi ti ẹya ṣe.

Wọn ní akikanju ẹdá ni Ọjọgbọ́n Adesanmi, ẹni to ṣetan láti jàjà ominira fun ilẹ adúlawọ nípa kíkọ ìwe ati ṣise ìlanilọye fun àwọn ọdọ.

Wọn fi kun pé, ohun ti Nàìjíríà sọnu nípa ẹni to ku yìí kii ṣe ńkan to ṣe fẹnu sọ tan.