Ọwọ́ Amotekun Ondo tẹ ọmọ ọdún 16 tó fi ipá bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀

Ikọ Amotekun ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan lori ẹsun pe o fi ipa ba iyawo ẹgbọn rẹ atawọn obinrin mẹsan an mii lopọ.

Adari ikọ Amotekun ipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye sọ pe ẹgbọn afurasi ọhun ko si nile lasiko to ba iyawo rẹ lopọ.

Nigba to n fi oju afurasi naa atawọn afurasi mii lede, Adeleye ni ṣe ni ọmọdekunrin ọhun wọ inu ibusun ẹgbọn rẹ, to si ri iyawo ẹgbọn rẹ to n sun ni ihoho, to si fi ipa ba lopọ.

Inu yara wọn ni mo ti maa n fipa ba wọn lopọ

Nigba ti afurasi naa n ba awọn akọroyi sọrọ, o ni lootọ loun ba iyawo ẹbọn oun lopọ, pẹlu awọn obinrin mẹsan an mii ni abule kan ni Laosun, to wa ni Iwọ oorun ipinlẹ naa.

O ni “Ni Laosun, mo fipa ba obinrin mẹsan an lopọ, ọjọ ori awọn mii ninu wọn ko ju ọdun mọkandinlogun si marundinlọgbọn lọ.”

“Ni ṣe ni mo maa n lọ sinu yara wọn, ti mo si maa ba wọn lopọ.”

“Mi o ki n lo ibọn tabi ọbẹ lati dunkoko mọ wọn.”

“Nigba mii, ọwọ wọn maa n tẹ mi, ti wọn a si fi mi silẹ lẹyin ti wọn ba ti kọkọ lu mi daadaa.”

“Ọlọpaa ti mu mi ri... wọn mu mi nitori mo lọ ji epo pupa oni lita marundinlọgbọn nigba ti mo n ko owo jọ lati ra ẹro ibaraẹnisọrọ.”

Adeleye ni afurasi naa yoo foju bale ẹjọ laipẹ lẹyin ti Ametekun ba pari iwadii rẹ tan.