You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tó n gbé àṣà Yorùbá lárugẹ́ sọ nkan tó jẹ́ ìwúrí fún tó fi n ṣe bẹ̀ẹ́
Demilade Lijoka, ọmọ ọdun mẹsan-an to n ki oriki ilu abinibi rẹ ni ede Yoruba.
Ọdọmọde naa sọ fun BBC pe lati kekere ni ede abinibi rẹ, Ikalẹ, ti dun bi oyin lẹnu oun, paapaa nipasẹ bi awọn obi rẹ agba ṣe ma n ṣe iwuri fun lati ma a sọ.
O ma n fi ede Ikalẹ yii gba awọn eeyan ni imọran, ikini fun ọjọ ibi, ati bẹẹ bẹẹ lọ lori ayelujara Instagram ati Tiktok.
Ori ayelujara yii lo ti wa a di gbajumọ pede-pede ti awọn eeyan ma n gba ti ẹ.
Ọmọ ọdun mẹsan-an naa sọ pe lati kekere ni oun ti fẹran awọn nkan ibilẹ.
Demilade sọ pe idunnu lo jẹ nigba ti awọn obi oun fi fidio akọkọ ti oun ṣe nipa ewi pẹlu ede Ikalẹ si ori ayelujara, nitori pe ọjọ ti pẹ ti oun ti fẹ ma a gbe aṣa jade.
"Lẹyin ti fidio naa gba gbogbo ori ayelujara, ni baba mi wo o pe asiko ti to fun mi lati gbe ẹbun atinuda mi jade fun araye rí."
- Ọdùn kẹwàá ni mo tó rín, ojú ri tó ṣùgbọ́n ẹ má sọrètí nú lórí ọmọ àkàndá ẹ̀dá- Oriogbade
- Akẹ́kọ̀ọ́ LASU láàrọ́ọ̀, Mọkálíìkì lọ́sàn án, ẹni tó ń ṣe bàtà lálẹ̀ ní mí- Olamide
- Ọtí àti sìgá ni mo fi bẹ̀rẹ̀ kí igb'ó mímu tó dá ìrìnàjò mi rú, mo kábàámọ̀- Busayo
- Ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ògbóntagí èdè Yorùbá, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko
Ọmọdebinrin naa sọ pe kii ṣe nitori owo, tabi nitori ẹ̀bùn gbigba ni oun ṣe n gbe ede Yoruba, paapaa Ikalẹ larugẹ lori ayelujara.
O ni afojusun oun ni lati ri pe awọn eeyan ko gbe aṣa ibilẹ wọn ju si ibi kan.
"Mi o fẹ ka gbagbe aṣa ibilẹ wa."
O ni nkan ti oun n ṣe yii ko ṣe idiwọ fun eto ẹkọ oun rara, nitori pe baba oun ti ṣe ilana bi oun yoo ṣe ma a ṣe gbogbo rẹ ti wọn ko fi ni di ara wọn lọwọ.
Demilade Lijoka ni oun gba awọn obi ti kii fẹ ki ọmọ wọn sọ ede Yoruba ni imọran pe, ki wọn dẹkun lati ma a ṣe bẹẹ.