Ọba Yoruba lórílẹ̀èdè Togo, Abdlkareem Afolabi Amon-lòkò wàjà

Oríṣun àwòrán, JIBRIL YAHDAFIU
Eerin wo nilu Lome, lorilẹede Togo lẹyin ti Kabiesi Ọba Oodua, Alhaji Abdlkareem Afolabi Amon-lòkò kini, to jẹ Ọba Yoruba nibẹ waja.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, ni Ọba Yoruba naa waja.
Wọn ti ṣeto isinku ori ade naa ni ilana ẹsin Musulumi.
Kabiesi Abdlkareem Afolabi Amon-lòkò kini, jọ ọmọ bibi ilu Ejigbo, baba won ni ọmọ orilẹede Naijiria lati ilu Ejigbo nipinlẹ Osun.
Ọmọ ile Amon-lòkò ni wọn jẹ lati adugbo Ayeogbo niluu Ejigbo, ti iya wọn si jẹ ọmọ bibi Masifa.
Oloogbe naa oniṣowo eto irinna ati oniṣowo pako ati igi gẹdu, o si jẹ oniṣowo to gbajumọ lati ilẹ adulawọ titi de ilu awọn alawọ funfun.
Wọn bi oloogbe naa si adugbo Anfunè ni orilẹede Togolome.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2011 ni wọn de e lade gẹgẹ bii Ọba Yoruba niluu Togo.
Lẹyin iwuye rẹ ni wọn tun fi jẹ olori Ọba Yoruba lorilẹede Lometogo.
Ẹni ọdun mọkandinlaadọrin ni ori ade naa ki ọlọjọ to de.
Ọpọ ọmọ, atawọn ọmọ-ọmọ lo gbẹyin Ọba Ọba Oodua, Alhaji Abdlkareem Afolabi Amon-lòkò kinni.















