China yóò kojú ẹ̀sùn ìfìyàjẹ jẹ Mùsùlùmí àti ẹ̀yà tó kéré - UN

Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN ti fi ẹsun kan orilẹede China wi pe o ṣeeṣe ki ko foju wina ofin lori ẹsun ifiyajẹ ọmọ eniyan ni agbegbe Xianjiang.

Ajọ UN ni o ti le ni ọdun kan ti wọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun naa, amọ ti orilẹede China di wọn lọwọ pẹlu ẹsun pe irọ ni iwadii naa.

Ọpọ igba ni China ti ni ki wọn mase fi iwadii naa sita, ti wọn si pe ni idukokomọni lati ọwọ awọn orilẹede oke okun.

Ki ni o wa ninu iwadii naa?

Iwadii ti Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN naa gbe jade fi lede pe awọn Musulumi to wa ni agbegbe Uyghur, ni wọn n fi iya jẹ, eleyii to jasi ifiyajẹni lọna aitọ.

Wọn fẹsun kan China pe iwadii ọhun fihan pe wọn nlo ofin orilẹede naa ti ko lẹsẹ nlẹ, lati fi tẹ ẹtọ awọn eniyan mọlẹ.

Paapaa awọn ẹya tabi ẹsin ti wọn kere nibẹ.

Ajọ UN ni bi o tilẹ jẹpe awọn ko le e sọ iye awọn eniyan ti wọn ti fi iya jẹ, o kere tan, o le ni miliọnu kan eniyan ti wọn wa ni ahamọ ni agbegbe Xianjiang, ni iha ariwa orilẹede China.

Ẹsun ti wọn fi kan China nipe wọn tun ma n fi ipa ba awọn eniyan naa lopọ, to fi mọ fifi iya jẹ ni nitori ẹya.

Bakan naa ni wọn n fi ipa mu awọn eniyan lati ṣe ifeto si ọmọ bibi ni agbegbe naa, ti wọn si n gbe wọn lọ si ileewosan fun ayẹwo ati itọju tipatipa.

A faramọ iwadii naa ki agbaye dide iranwọ fun wa – Ajọ ajafẹtọ

Ajọ Ajafẹtọ World Uyghur Congress ninu atẹjade ti wọn gbe jade ni wọn ti gboriyin fun iwadii Ajọ UN naa ti wọn si ni lootọ ni iṣẹlẹ ifiyajẹni naa n waye nibẹ.

Bakan naa ni wọn fikun un pe ki awọn orilẹede lagbaye dide fun iranwọ wọn, ki wọn si doola ẹmi awọn eniyan to n la ifiyajẹni kọja lọwọ orilẹede China.

Amọ orilẹede China ni irọ ni ẹsun naa ati wipe igbesunmọni ni awọn n koju ni agbegbe Xianjiang naa.

O kere tan o le ni miliọnu mejila awọn ẹya Uyghurs to n gbe ni Xinjiang, ti pupo ninu wọn si jẹ Musulumi, amọ awọn ti kii ṣe Musulumi naa n faragba ninu ifiyajẹni to n waye ni agbegbe ọhun.