You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé ìṣẹ́ ààbò ọ̀pá epo fún Tompolo mú ìfura dání - Akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti koro oju si ilana ti ijọba apapọ gba gbe iṣẹ agbaṣe fun ileeṣẹ alaabo aladani kan, to jẹ ti ajijagba lẹkun Niger Delta nigba kan, Government Ekpemupolo, Tompolo.
Iroyin sọ pe biliọnu mẹrin Naira ni ijọba yoo ma a san fun iṣẹ naa loṣooṣu.
Ninu atẹjade to fi si ori Facebook rẹ lọjọ Ọjọru, Gomina Akeredolu sọ pe o jẹ iyalẹnu bi ijọba apapọ ṣe gbe iṣẹ fun iru ileeṣẹ alaabo bẹẹ.
Laipẹ yii ni iroyin jade pe ijọba apapọ Naijiria, ti gbe iṣẹ fun ileeṣẹ alaabo kan to jẹ aladani, lati ma a ṣọ awọn ọpa eporọbi ni ẹkun Niger Delta.
Eyi ni ijọba ni yoo dena bi awọn kan ṣe ma n fọ awọn ọpa epo ni agbegbe naa.
Ṣugbọn nigba to n fi ero rẹ han lori igbesẹ yii, Akeredolu sọ pe o fihan pe ijọba Naijiria ti faaye gba awọn ajọ ati ileeṣẹ ti kii ṣe ti ijọba, lati ma a lo awọn nkan ija oloro, ti ko si fun awọn ipinlẹ niru anfaani bẹẹ.
“Gbigbe iṣẹ fun ileeṣẹ aladani lati mojuto ipenija eto aabo fihan pe gbogbo ilana ijọba fun aabo nilo atungbeyẹwo.”
Oludari NNPC, Mele Kyari ni igbesẹ ijọba ko buru
Amọ ninu ọrọ to fi gbe igbesẹ naa lẹsẹ, Oludari ileeṣẹ eporọbi ni Naijiria, Mele Kyari, sọ pe kii ṣe igba akọkọ niyii ti ijọba gbe iṣẹ pipese aabo fun awọn ọpa epo, fun awọn araalu ni ẹkun Niger Delta.
O ni anfaani araalu ni igbesẹ naa wa fun.
Kyari ni lootọ ni awọn ileeṣẹ laabo to jẹ ti ijọba, n gbiyanju, ṣugbọn amojuto atigba-degba fun awọn ọpa eporọbi nilo ki awọn ileeṣẹ aladani ati awọn alẹnulọrọ laarin ilu dasi.
Akeredolu ni lati ọjọ ti awọn ijọba ipinlẹ ti n beere fun anfaani lati ra awọn nkan ijagun fun awọn ajọ alaabo to da silẹ, ni ijọba apapọ ti n kọ̀.
“O jẹ nkan to mu ọpọlọpọ ifura dani, bi ijọba ko ṣe gba awọn ijọba ipinlẹ laaye fun iru nkan bẹẹ, ṣugbọn to fun awọn ileeṣẹ aladani laaye, botilẹ jẹ pe fun aabo araalu ni awọ̀n gomina ṣe n gbe igbesẹ.”
Ẹwẹ, Gomina Akeredolu ni gbogbo igbiyanju awọn lati mu ki ijọba ṣe atunto eto aabo to wa nilẹ, lo ja si ofo, botilẹ jẹ pe ilana naa ko so eso rere.
Awọn gomina, paapaa nilẹ Yoruba, da ileeṣẹ alaabo silẹ ti wọn pe ni Amotekun.
Wọn ni eyi jẹ igbesẹ lati mojuto eto aabo to mẹhẹ ni ipinlẹ wọn.
Ṣaaju ki ajọ Amotekun to bẹrẹ, ọpọ ija ati itahunsira lo waye laarin awọn gomina ni Iwọ oorun Gusu Naijiria ati ijọba apapọ.
Ti ijọba apapọ si ko si fi ara mọ igbẹsẹ awọn gomina naa.
Taa ni Government Tompolo?
Ọgbẹni Government Oweizide Tompolo, jẹ gbajugbaja ajijagbara ninu ẹgbẹ ajijagbara Movement for the Emancipation of the Niger Delta (MEND).
Ẹgbẹ naa jẹ akojọpọ awọn agbebọn to jẹ ikọ to ma n ji awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eprọbi gbe, ti wọn si tun ma n fọ awọn ọpa epo ni aarin ọdun 2006 si 2009.
Ẹgbẹ MEND sọ pe afojusun oun ni lati ja fun ẹtọ awọn araalu ni ẹkun naa, nibi ti eporọbi Naijiria sodo si julọ, nitori bi ijọba ati awọn ileeṣẹ ifọpo ko ṣe nani wọn.
Ọpọlọpọ ọdun ni ija fi n waye laarin ijọba Naijria ati awọn ọmọ ẹgbẹ MEND.
Ṣugbọn lasiko iṣejọba oloogbe Umar Yar’Adua gẹgẹ bi aarẹ Naijiria, o da eto idariji silẹ fun awọn ajijagbara to ṣetan lati jọwọ nkan ija wọn.
Lara awọn to si janfaani eto naa ni Tompolo wa.
Obitibiti owo ni ijọba ṣeleri fun Tompolo ati awọn ọmọ ikọ rẹ ti wọn ba gba.
Lẹyin adehun to waye laarin wọ̀n, ijọba forijin wọn.
Koda o tun ṣeto imupadabọsipo fun wọn lọdun 2009.
Yatọ si Gomina Akeredolu, ọpọ eeyan mi lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba.
Koda, ẹgbẹ awọn ọdọ kan ni Ariwa Naijiria, The Amalgamated Arewa Youths Group (AAYG) ṣeleri lati ṣe iwọde tako igbesẹ naa.