You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Á júwe ilé fún Niyi Akintola tó bá tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ tako wá - APC l‘Oyo
Ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo ti ni oun yoo yọ Oloye Niyi Akintola bii jiga kuro ninu ẹgbẹ naa lori ẹsun pe o n sọrọ kobakungbe nipa ẹgbẹ ọhun.
APC ni awọn ọrọ ti Akintola sọ lori ẹrọ redio kan lopin ọsẹ, pe ki awọn alatilẹyin oun dibo fun PDP ko bojumu.
Ninu atẹjade kan ti alaga wọọdu kẹsan an ni ijọba ibilẹ Ido, Ismail Babatunde fi lede, ni eyi ti jẹyọ.
Babatunde ni Akintola n ṣiṣẹ lodi si ẹgbẹ lẹyin to ke si awọn alatilẹyin rẹ lati dibo fun ẹgbẹ alatako ninu eto idibo to n bọ.
O ni “Ṣiṣe iṣẹ lodi si ẹgbẹ atawọn ọrọ kobakungbe ti Akintola n sọ ti to lati sọ pe ki a yọ kuro ninu ẹgbẹ, sibẹsibẹ, a ko ni ṣe bẹẹ, amọ a oo kilọ fun ko tun iwa rẹ ṣe.”
“Ṣugbọn ti Akintola ko ba jawọ ninu ṣiṣe iṣẹ lodi si ẹgbẹ, ko si ohun miran ti a oo ṣe ju pe ki a gbe igbesẹ lati yọ ninu ẹgbẹ naa ko to tu ẹgbẹ ọhun ka.”
Inu wa dun pe awọn alatilẹyin Akintola fi APC silẹ - Oyo Kajola Group
Ẹwẹ, ẹgbẹ kan, Oyo Kajola Group, OKG, ti gboriyin fun awọn alatilẹyin Akintola fun bi wọn ṣe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lati darapọ mọ PDP, paapaa lagbegbe oke Ogun.
Gẹgẹ bii ohun ti ẹgbẹ naa sọ, Akintola ti fi ara rẹ han gẹgẹ bii oloṣelu to mọ ohun to n ṣe bi ko ṣe fi ọrọ sabẹ ahọn sọ nipa APC.
Ninu atẹjade kan ti OKG fi lede, eyii ti adari rẹ, Adebayo Ayandele buwọlu, wọn ni ko ya awọn lẹnu pe awọn eeyan kan n dunkoko mọ Akintola nitori pe wọn korira otitọ.
‘Irẹwẹsi ti de ba APC, lo se n fi apa janu’
OKG ni irẹwẹsi ti de ba ẹgbẹ oṣelu APC, bi awọn alatilẹyin Akintola ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ lati darapọ mọ PDP, o si ti fun PDP lagbara si.
Wọn ni ariwo ẹnu lasan ni APC n pa lori awọn nnkan ti Akintola sọ lori redio kan lopin ọsẹ, ati pe opin ti n de ba ẹgbẹ oṣelu ọhun ni ipinlẹ Oyo.
Lẹyin naa ni wọn rọ Akintola lati maṣe tẹti si ohunkohun ti ẹgbẹ alatako ba n sọ nipa rẹ.
Amọ wọn ni ko fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọmọ ipinlẹ Oyo lati ṣiṣẹ ki gomina Seyi Makinde le wọle lẹẹkeji.
Mo ti gbe alaga wọọdu APC lọ sile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ, maa gba biliọnu kan naira lọwọ rẹ – Niyi Akintọla
Wayi o, Amofin agba Niyi Akintọla SAN, tii se eekan kan lẹgbẹ oṣelu APC, ti fesi sawọn ẹsun ti alaga wọọdu kan ni APC fi kan-an.
Akintola, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni oun ti gbe alaga wọọdu Iddo naa, Ismail Babatunde, lọ sile ẹjọ.
Alaga naa lo ni o fọwọsi iwe ti awọn kan lẹgbẹ oṣelu APC kọ pe ki wọn yọ oun kuro lẹgbẹ oṣelu naa.
Akintola ni ẹsun ibanilorukọjẹ ni oun fi kan alaga APC ni wọọdu naa, ti oun si n beere fun biliọnu kan naira owo itanran.
Akintola sisọ loju ọrọ yii lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori rukerudo to n waye lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ.
Oludije tẹlẹ sipo gomina nipinlẹ Oyo naa lo n fesi si iroyin kan to ni awọn kan lẹgbẹ oṣelu APC ti gbe igbesẹ pe ki wọn yọ ọ lẹgbẹ oṣelu naa.
Akintọla, tii se agba amofin (SAN) ṣalaye pe ko si ẹnikẹni to le e yọ oun lẹgbẹ oṣelu APC nitori pe oun n sọ ootọ inu oun jade.
‘Awọn eekan oloselu ninu APC ati Baalẹ Omi Adio ti bẹ mi lori ẹsun ibanilorukọjẹ naa’
Amofin Akintola, nigba to n sọrọ pe awọn eekan ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ ti bẹ oun lori lẹta ibanilorukọjẹ naa, O ni baalẹ agbegbe Ọmi Adio gan an ti da si ọrọ naa lati bẹ oun.
Agba oselu naa sisọ loju rẹ pe osisẹ kafinta ni alaga wọọdu to tọwọ bọ iwe naa ko si mọọ kọ tabi mọọ ka.
“Ko le ka nnkan to tọwọ bọ iwe fun. Ismaila lẹni to tọwọ bọ iwe naa. Ko tilẹ lee ka a.
A ṣẹṣẹ fun un ni iwe ipẹjọ ẹsun ibanilorukọjẹ ni, ti owo itanran ti a beere fun si jẹ biliọnu kan naira.”
‘Nitori Tinubu ni ọpọ ṣi fi duro si ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ’
Amofin Niyi Akintọla SAN tun ṣalaye pe nibi ti ọrọ de duro ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ bayii, o daju, oun si lee fi ọwọ rẹ sọya pe ẹgbẹ oṣelu naa yoo fidi rẹmi ni idibo gomina lọdun 2023.
Eekan agbẹjọro naa, to ti lewaju igbẹjọ to gbe ọpọlọpọ gomina ati awọn oloṣelu miran de ipo iṣejọba lorilẹede Naijiria sọ pe, oun ko bẹru boya ẹnikẹni fẹ le oun kuro lẹgbẹ APC nitori ko si ere kan ti oun jẹ nibẹ, nigba ti wọn ko le oun gan.
O ni ohun to ṣi n mu ki oun atawọn oloṣelu onilana itẹsiwaju ‘Progressives’ kan ṣi duro sinu APC nipinlẹ Ọyọ, ko ju lati ṣe iṣẹ ati atilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, to n dije fun ipo aarẹ lọ.
'Fọlarin ko le wọle nipinlẹ Ọyọ, koda ko le ri ipo kẹta di mu'
Amofin Akintola ni gbogbo awọn lawọn mọ daju pe oludije fun ipo gomina ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ, iyẹn Sẹnetọ Teslim Fọlarin, ko lee bori nibi idibo naa, ‘koda ko le ṣe ipo kẹta’.
O ni gbogbo awọn oludije lẹgbẹ oṣelu naa ni wọn n ni ikunsinu si Sẹnetọ Fọlarin.
O ni ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ̀ Ọyọ ti di ti iru wa- ogiri wa, ogiri wa, to bẹẹ gẹ to fi jẹ pe gbogbo awọn to gbe ẹgbẹ ro, ti wa di epo ẹgusi ti wọn ko fẹ ji ri mọ.
Bakan naa lo ni igbesẹ awọn eeyan kan lati gba ẹgbẹ oṣelu miran lọ lati lee ri ọna ati gba tikẹti idije wa lara koko afẹnuko ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa to n fapa janu fẹnu ko si.
Amofin Akintọla ni koko afẹnuko kẹfa leyi, alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ Saki-West, Họnọrebu Nathaniel Akano lo si fi sinu afẹnuko wọn pe ‘idalu ni iṣelu o.
O ni ibikibi ti olukaluku oloselu ba ti maa ri tikẹti idije, ni ko lọ gba lọ’.