Ṣíṣe ayẹyẹ ọdùn 100 Ọba ti àwọn òyìnbó lé kúrò ni ìlú

    • Author, Barnaby Phillips
    • Role, Kumasi
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ ero lo wa ni ita aafin Kumasi lorilẹede Ghana, ti wọn n se ayẹyẹ ọgọrun un ọdun ti Ọba ilu naa, Prempeh ti awọn oyinbo ilẹ gẹẹsi le kuro ni ilu pada si ile.

Prempeh jẹ Ọba Asante tabi Asantehene to kọ lati tẹwọ gba ofin ilẹ Gẹẹsi lati gba ilẹ rẹ.

Awọn ọmọ oogun Ilẹ Gẹẹsi rin irin igba kilomita lọ si ilu Kumasi ni ọdun 1896, ti wọn si mu Prempeh ati awọn aadọta ninu mọlẹbi rẹ, awọn oloye ati awọn ẹru gẹgẹ bi ẹlẹwọn, ti wọn si tun ko dukia aafin.

Awọn eeyan yii ni wọn gbe lọ si Elmina, ko to di pe wọn fi ọkọ oju omi gbe wọn lọ si Sierra Leone, ni ọdun 1900, wọn tun gbe wọn lọ si Seychelles.

Nigba to di ọdun 1924, ijọba UK gba pe ki Prempeh pada si ile, to si ti di arugbo nigba to pada si ile ni Kumasi, to n wọ aṣọ ebo ati fila.

Itan ibanujẹ ni eyi sugbọn o jẹ eyi to wuni lori pupọ.

“Ijọba UK se gbogbo ohun ti wọn le se ṣugbọn wọn ko ri ẹyin Asante,” eyi ni ariwo ti awọn eeyan to wa ni ita n pa.

Asantehene lọwọ yii, Osei Tutu 11 naa darapọ mọ awọn eeyan nibi ayẹyẹ naa pẹlu ọpọ goolu lọrun rẹ, ti wọn si n lu ilu tẹle.

Aṣa Asante ko di ohun igbagbe.

Bi ti lẹ jẹ pe bi wọn se gbe Prempeh kuro ni ipa nla ni ilu Asante ati Seychelles ni ọna ti awọn oyinbo asiko naa ko lero

Eeyan jankan to wa ni ayẹyẹ naa ni, to waye ni Kumasi ni opin ọsẹ ni Aarẹ Wavel Ramkalawan, ẹni to ni”Iwuri nla ni bo ti lẹ jẹ pe o ba ni lọkan jẹ fun wa lati pada Ọba wa.

“O ṣafihan ọwọ to ni fun awọn eeyan wa ati pe o tun tẹwọgba ifẹ ni Seychelles.”

Apẹẹrẹ yii to wa ninu mọlẹbi yii ni ọpọ eeyan n duni si lonii.

Ọmọọba Mary Prempeh Marimba jẹ ọmọ-ọmọ Prempeh. Baba- baba rẹ, jẹ ọmọ Prempeh fẹ obinrin Seychelles, ti wọn si jọ duro ni ori omi naa ki baba to gbera kuro.

Mary jẹ alamojuto nọọsi ni olu ilu Victoria, to gbera lọ si Kumasi pẹlu ọmọ rẹ Suzy lati darapọ mọ awọn eeyan to n se ayẹyẹ Asante.

“ Baba- baba mi ni ọpọ idojukọ, to si jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ, ṣugbọn mo wa lati wa ba awọn eeyan wa ati mọlẹbi mi yọ

“Awọn eeyan Asante to n gbe ni Seychelles n gbe ni ilu kan ti orukọ rẹ jẹ ‘Ashanti Town

Prempeh gbe ni agbegbe naa, ti wọn si fun ni iọwọ ati apomle, gẹgẹ bii Dr Penda Choopy se sọ.

Lasiko to wa ni ibẹ, o kọ bi wọn se kọ iwe ati ka iwe, to si tun rọ awọnm Asante pe ki wọn lọ si ile ẹkọ.

Bakan naa lo gba ẹṣin kristẹni sugbọn ko se ni dandan pe ki awọn yooku tẹle oun.

Ni ọdun 1918, o kọ lẹta si Oba George pe ki wọn gba laaye pe ki o pada si ile.

O wa ni ẹwọn fun ọdun mejilelogun.

Lẹyin ọdun diẹ, nigba ti wọn ri pe Prempeh ti fé ku, ti eyi si le fa wahala, wọn gba ko lọ si ile.

Prempeh ku ni ọdun 1931, ti Prempeh keji si bọ sipo ni ọdun1935.

Ni abule kan ni to jẹ wakati kan si Kumasi, mo pade iya agba kan to jẹ ọmọ-ọmọ Prempeh.

“Emi nikan mo ku ninu awọn eeyan ti wọn bi si Seychelles, mo jẹ ọmọ orilẹede Ghana ati Seychelles - Ọmọ ọdun marun un ni mi nigba ti mo pada.

“Ti mo ba rin niluu, awọn araalu yoo ma ki mi pe ọmọ ọba, bawo ni? Ọmọ ọba, vini, vini, tou i byen.

Wiwa Molly lo kun fun ọpọ ironu. O ma lọ si ori oori iya rẹ Hugette, ẹni to gbe wa ni ọdun 1948.

Hugette pada si Seychelles nibẹ lo ku si.