Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Eagles pẹ̀lú Tunisia máa lágbára àmọ́ a máa borí wọn - Akọ́nimọ̀ọ́gbá àti Balogun Super Eagles sọ̀rọ̀ akin

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Éric Chelle, ti sọ pe lotitọ ni ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye laaarin orilẹede Naijiria ati Tunisia yoo lagbara, ṣugbọn o da oun loju pe Super Eagles yoo bori.
Chelle sọ eyi nigba to n dahun ibeere akorọyin BBC niluu Fes, lorilẹede Morocco, nibi ti idije AFCON 2025 ti n waye.
Ọla ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025 ni Tunisia yoo ma wọya ija pẹlu Naijiria, ni papa iṣere Fes, ni Morocco.
Tẹ o ba gbagbe, orilẹede Tunisia lo fọwọ osi juwe ile fun Naijiria ni ipele kẹrindinlogun (Round of 16 ) lọdun 2021, lorilẹede Cameroon.
"Ifẹsẹwọnsẹ nla ni eyi maa jẹ, sugbọn mo nigbagbọ nla ninu awọn agbabọọlu mi pe wọn yoo fakọyọ."
Bẹẹ ni Chell wi.

A mọ ohun tí yoo mu inu awọn ololufẹ Super Eagles dun -Ndidi, Balogun Super Eagles
Bakan naa ni Balogun ikọ Super Eagles, Wilfred Ndidi, sọrọ idaniloju nipa ifẹsẹwọnsẹ to n bọ naa.
Wilfred Ndidi wa lara ikọ Super Eagles ti Tunisia fiya jẹ lọdun 2021 ni Cameroon.
"Ipadanu nla ni ifẹsẹwọnsẹ naa lọdun 2021, sugbọn iyẹn ti lọ, igba tuntun ni eyi fun ikọ Super Eagles ati awọn agbabọọlu tuntun.
"Ko si ẹnikẹni ti ko fẹ gba Ife ẹyẹ AFCON yii laarin wa, sugbọn aseyọri nla ni yoo jẹ fun wa lati gba a"
Ndidi dupẹ lọwọ awọn araalu ati awọn ololufẹ Super Eagles fun atilẹyin wọn, o si jẹ ko di mímọ awọn mọ nnkan patọ ti yoo mu inu awọn ololufẹ Super Eagles dun, iyẹn naa si ni jija ewe olubori ni AFCON 2025.
"Ohun iwuri ni atilẹyin awọn ololufẹ Super Eagles jẹ fun wa.
"A mọ pe aseyọri nla lo maa mu inu awọn ololufẹ Super Eagles dun."














