Bí ẹ bá rí Kẹ̀kẹ́ tí kò ní lo epo rárá, ṣé ẹ ó rà á? Ẹ wo àwọn àrà ọ̀tọ̀ Kẹ̀kẹ́ akẹ́rù yìí

Ẹ kan ro o pe ko si epo ni adugbo yin tabi ki o wọn gogo kọja agbara gẹlẹ bi owo naira ṣe di goolu lasiko yii lorilẹede Naijiria, ipa wo ni yoo ni lara ẹbi ati ọrọ aje?

Gbogbo nnkan lo gbowo lori lasiko yii torinaa, eto irina gan yoo gunpa.

Eyi lo mu ki awọn ọjọgbọn onimọ ẹrọ kan eyi ti Ọgbẹni Tolulope dari ṣe agbejade awọn Kẹkẹ akẹru ti ko ni maa ya ile epo rara ayafi ko maa gba itansan oorun sara lati ṣiṣẹ.

“Ti a ba le gbe e silẹ fun awọn ọlọja to jẹ pe nnkan ti wọn fi n rin, ko ni lo epo mọ, a jẹ irọrun fun wọn.”

Tolulope ṣalaye pe lẹyin iriṣẹ kan ṣoṣo ti ko si nilẹ yii, gbogbo nnkan lawọn n ra ni Naijiria.