Ọmọ ọdún mẹ́rin jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n fipá ba lòpọ̀

Inú ìbànújẹ́ ni àwọn ẹbí ọmọ ọdún mẹ́rin, Khadijat Adamu wà báyìí lẹ́yìn tí ọmọ náà jáde láyé.

Àwọn òbí ọmọ náà ní tó bá ṣeéṣe kí àwọn fọwọ́ aago sẹ́yìn àwọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi ra ẹ̀mí wọn padà sáyé.

Ní ìpínlẹ̀ Kano ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

"Ìdí Khadijat ń rùn nígbà tí ìyá rẹ̀ ń wẹ̀ ẹ́, la ṣe fura pé nǹkan ti ṣe é"

Bàbá Khadijat tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Adamu Mohammed ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án ni àwọn fura wí pé ojú ara Khadijat ń rùn, nígbà tí wọ́n ń wẹ̀ ẹ́.

Mohammed ní nígbà tí ìyá ọmọ náà ń wẹ̀ ẹ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà, ló ṣàkíyèsí pé ojú ara rẹ̀ ń rùn.

O ní òun bá gbìyànjú láti ba fọ ojú ibẹ̀, igbé ó ń dun òun ni ọmọ náà ń pariwo.

“Ìgbà náà la tó mọ̀ wí pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Khadijat, tí ìyá rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ si gan-an ní pàtó.”

“Ó sọ wí pé ara ilé wa kan ló fún òun ní bisikíìtì láti fi tan òun wọ inú ilé rẹ̀, tó sì ní kí òun bọ́ pátá òun kó tó fi ipá bá òun lò pọ̀.

Bakan naa lo ni ọkunrin naa tún dúnkokò mọ́ òun wí pé òun kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.”

Mohammed ní Khadijat ṣàlàyé pé ará ilé àwọn náà sọ fún òun pé òun máa pa òun, tí òun bá bá ẹnìkankan sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.

Ó ní ìdí rèé tí òun kò fi ṣàlàyé fún àwọn òbí òun.

Àyẹ̀wò dókítà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fi ipá bá Khadijat lò pọ̀

Ó ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn gbé Khadijat lọ sí ilé ìwòsàn tí dókítà si fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹnìkan ti fipá bá ọmọ náà lòpọ̀ ní tòótọ́.

Mohammed tẹ̀síwájú lẹ́yìn tí àwọn dókítà ti fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ni àwọn ti gba àgọ́ ọlọ́pàá lọ láti lọ fi ẹjọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sùn.

Ó ní àgọ́ ọlọ́pàá Hudu ni àwọn ti lọ fi ẹjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà sùn tí àwọn ọlọ́pàá náà sì jòkòó láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọmọ tó sì ṣàlàyé gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún wọn.

Khadijat jáde láyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì

“Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí a mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ìyẹn ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án ni Khadijat bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àìsàn nígbà tí a sì ma fi gbe dé ilé ìwòsàn dókítà ní ó ti papòdà.

Ó ní kí ọmọ náà tó kú ohun tí ọmọ náà ń pariwo tí àwọn ará ilé yòókù náà gbọ́ ni pé “ó máa pa òun”, èyí tó jẹ́ ohun tí ọkùnrin náà sọ fún ọmọ náà kó tó fipá ba lòpọ̀.

Mohammed ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí àwọn ti kọ́kọ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá ti fi póró òfin gbé ọkùnrin náà.

Ó ní ẹni tí òun mọ̀ dada ni, tí àwọn jọ máa ń sọ̀rọ̀ dada ní àdúgbò ni ẹni tó ṣe iṣẹ́ láabi náà.

Ó fi kun pé ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu f;ún òun wí pé ọkùnrin náà le hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ pàápàá sí ọmọ òun.

Mo ní àfojúsùn tó ga fún ọmọ ni àmọ́ wọ́n ti kán mi ní eyín ọ̀ọ́kán – Mohammed

Mohammed ní òun ní àfojúsùn fún Khadijat nítorí ọmọ tó jáfáfá ni.

Ó ní ohun tó wu òun ni kí ọmọ náà di dókítà ní ọjọ́ iwájú nítorí pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin kó tó ṣe aláìsí ó ti ń há Kúránì sórí.

Ó tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni òun kò le gbàgbé nípa ọmọ náà nítorí gbogbo ìgbà tí òun bá wọlé láti òde ni ọmọ máa ń sáré wá pàdé òun lẹ́nu ọ̀nà láti kí òn káàbọ̀.

Ó ni òun ni àkọ́bí ọmọ òun àti pé àwọn méjì péré náà ṣì ni àwọn ọmọ tí àwọn ti bí.

Bákan náà ló rọ àwọn aláṣẹ àti ìjọba láti fojú ẹni tó ṣiṣẹ́ ibi náà wíná òfin àti pé òun ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ náà.

Lóòótọ́ ni ọkùnrin náà fipá bá Khadijat lòpọ̀ àmọ́ à ń retí èsì àyẹ̀wò àwọn dókítà - Ọlọ́pàá

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Haruna Kiyawa ní àwọn ti fi ọkùnrin náà ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì sí àhámọ́ nígbà tí àwọn dókítà ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó fipá bá Khadijat lòpọ̀.

Kiyawa ní àwọn ti gbọ́ si pé ọmọ náà ti jáde láyé ṣùgbọ́n àwọn ń dúró de èsì àyẹ̀wò láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú ọmọ náà gangan.

Ó ní ìwádìí àwọn ń lọ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan lórí ikú ọmọdé náà.

Ó fi kun pé kété tí ìwádìí àwọn bá ti parí ni àwọn yóò gbé afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́.