Ọlọ́pàá hú òkú ọkùnrin kan lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bí san mílíọ̀nù méjì náírà owó ìtúsílẹ̀

Ileese olopaa ipinlẹ Rivers ti hu oku arakunrin kan ti oruko rẹ jẹ David Kalu Onyems, lẹyin ti o kosi ọwo awọn ajinigbe lojo kokandilogun oṣu karun un.

Onyems ni o bo si ọwọ awọn ajinigbe lenu ibode ipinlẹ Abia ati ipinlẹ Rivers ni apa guusu orilede Naijiria.

Awọn mọlẹbi arakunrin naa ni awọn san owo itusile toto miliọnu meji naira fun awọn ajinigbe, ti wọn si tun se iku paa aburo awọn.

Kọmiṣọnna fun ileese olopaa ni ipinlẹ Rivers, Friday Eboka ni ọjo keji oṣu kefa ni ọwọ olopaa tẹ okan lara afurasi to lọwọ ninu ise buruku naa.

Eboka ni afurasi naa lo siwaju awọn olopaa lo si ibi ti wọn sin arakunrin naa si, ti awọn olopaa si ti gbe oku naa lo si ile oku.

“ A ti gbe oku arakunrin naa lo si ile oku lẹyin ti okan lara awọn afurasi siwaju wa lo si ibi ti wọn sin Onyems si

“Esi ayẹwo oku naa ni ileese olopaa duro de lati tẹsiwaju ninu iwadi wọn”

Ẹgbọn oloogbe naa, Tony Kalu ti ra ọwọ ẹbẹ si ijọba ati ileese olopaa lati fi ida ofin mu awọn ajinigbe naa.

Kalu ni o ba oun lọkan jẹ pe pẹlu owo toto milonu meji ti awọn san fun awọn ajinigbe naa, wọn se iku pa aburo awọn.

“iku aburo mi jẹ ọfọ areraya fun idile wa nitori o fi iyawo ati ọmọ merin sile.”

Ọwọ ileese olopaa ti wa tẹ awọn afurasi mesan to lowo ninu ijinigbe naa

Oruko awọn afurasi ajinigbe naa ni Ubong Emmanuel, Kenneth Owhonda, Mercy Idoh, Goodness Kalu Smart, Dennis Igwe, Ibenta Oha,Idaraesit Emmanuel Kpene, ati Favour John.

Comisona Eboka ni awọn olopaa ba ibon Ak47 ati ibon kekere kan lọwọ awọn afurasi naa.