You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Ìréjẹ wà nínú bí wọ́n ṣe mu Comfort tí wọ́n kò mú Wasiu pẹ̀lú ''
Bi K1, iyẹn olorin Fuji, Wasiu Ayinde ṣe pitu ọwọ rẹ lọsẹ to kọja ni papakọ ofurufu to wa niluu Abuja to si jọ pe o mu un jẹ, ko ti i pe ọsẹ kan lẹyin rẹ ti obinrin kan, Comfort Emmanson, naa tun di ẹni ti ihooho rẹ kari aye ni papakọ ofurufu Uyo.
Bo tilẹ jẹ pe fidio ṣafihan ibi ti Comfort ti n ba awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ṣe agidi, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe ki lo de ti wọn sare gbe e lẹsẹkẹsẹ lọ si atimọle lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ọlọkọ ofurufu naa fi ọmu rẹ hande tan.
Wọn ni Wasiu to di baaluu lọna si n yan fanda kiri igboro.
Ọpọ awọn alẹnulọrọ ninu oṣelu ni wọn ti koro oju si eyi, bẹẹ ni awọn mi-in n sọ pe ẹṣẹ ti Wasiu ṣe labẹ ofin, buru ju ti Comfort lọ.
Ẹsun wo gan-an ni wọn tilẹ ka si obinrin yii lẹsẹ, ṣe awọn to fi ọyan rẹ han jẹbi, abi ọlọmu funra rẹ ti ko wọ kọmu ni ko ṣe daadaa.
Ṣe bi wọn ṣe fipa gbe e lai wo ti pe ohun ẹlẹgẹ ni obinrin tọna?
Ta a ni ẹṣẹ rẹ buru ju labẹ ofin ninu Wasiu ati Comfort ?
Oju wo ni awọn amofin fi wo iṣẹlẹ yii lapapọ?
BBC News Yoruba kan si Amofin Festus Adedayo, lati ṣalaye awọn ibeere yii.
''Lábẹ́ òfin, ẹ̀ṣẹ̀ tí Wasiu Ayinde ṣẹ̀ làgbára ju ti Comfort lọ''
Gẹgẹ bi Amofin Festus Adedayo ṣe ṣalaye, o ni Wasiu ati Comfort huwa to lodi labẹ ofin.
Ṣugbọn ẹṣẹ ti Wasiu Ayinde ṣẹ, lagbara pupọ ju ti obinrin ti awọn eeyan sọ di KWAM 2 yii lọ gẹgẹ bo ṣe sọ.
''Bi eeyan ba gbiyanju lati da baaluu to fẹẹ fo duro, wọn le fi ẹsun kan an pe o fẹẹ ja ọkọ ofurufu naa gba, ati pe o fẹẹ sé awọn to wa ninu ọkọ naa mọbẹ ki wọn ma le jade.
''Abala 83 of NCAA Act 2022, Art .1 of 1979 lo fidi eyi mulẹ. Won si tun le fẹsun kan an pe o tẹ ẹtọ awakọ naa loju mọlẹ fun pe o da nnkan mimu si i loju.
Bẹẹ fun ti obinrin ti wọn ṣẹṣẹ mu yii, ohun ti wọn le sọ pe o ṣe naa ni pe o huwa ti ko tọ si awọn oṣiṣẹ-obinrin to wa ninu baaluu naa.
''Ìréjẹ wà nínú bí wọ́n ṣe mu Comfort tí wọ́n kò mú Wasiu pẹ̀lú ''
Nigba to n dahun ibeere nipa bi wọn ṣe sare fi Comfort ranṣẹ si gbaga, ti ko si ri bẹẹ fun Wasiu Ayinde, Amofin Adedayo so pe iwa irẹjẹ ni.
''O foju han kedere pe fifẹ ẹnikan ju ikeji lọ wa ninu ọwọ ti wọn fi mu ọrọ yii.''
''Kedere lo han pe olowo ṣe ohun gbogbo tan, iya ni yoo jẹ ọmọ talika lo n ṣẹlẹ.
''Ko yẹ ki Wasiu Ayinde kuro ni papakọ ofurufu yẹn pẹlu ominira, ta a ba wo bi ẹṣẹ to ṣẹ ṣe wuwo to. O han gedegbe pe aiṣododo ni wọn fi gbe Comfort, ti Wasiu si wa nile rẹ lominira.''
Lori ibeere pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ Ibom lo pe ọlọpaa ti wọn mu Comfort, ati pe Valuejet ko pe ọlọpaa fun Wasiu lo fi raye lọ, Amofin Adedayo sọ pe:
'' Koda, bi awọn ẹṣọ ileeṣẹ ValueJet ko ba mu Wasiu bi Ibom Air ṣe mu Comfort ni tiwọn, o yẹ ki awọn ọlọpaa orilẹede Naijiria ti pe e, ki wọn ti fọrọ wa a lẹnu wo fun ohun to ṣe.
''Ọna ti wọn gba gbe obinrin naa sọkalẹ ninu ọkọ ko daa''
Loju iwoye rẹ, Amofin Adedayo sọ pe bi wọn ṣe gbe obinrin naa sọkalẹ pẹlu ipa, ti gbogbo ọmu rẹ hande, ko daa.
O ni ọna ti ko ba ti ọlaju ode oni mu ni.
'' To ba jẹ pe ibi ti iriri ati òye wọn ti to ni, ọna ti wọn yoo gba gbe e ti ọmu rẹ ko ni i han bẹẹ yẹn wa ti wọn le lo.
Ǹjẹ́ obìnrin yìí jẹ̀bi ẹsun kankan?
Bi wọn yoo ba ka ẹsun si Comfort lẹsẹ, wọn le fi ti pe o tapa si bi won ṣe fẹẹ mu un kan an.
O lodi lati tako ofin nigba ti wọn ba fẹẹ mu ẹnikan.
Ibeere kan ṣoṣo to le waye ni pe, ṣe awon to fẹẹ mu un naa lẹtọọ lati mu un labẹ ofin, pẹlu awọn ti a ri ninu fidio to kari ayelujara.
Bẹẹ ni Amofin Adedayo ṣalaye.
Obinrin naa le pe ẹjọ tako ihoho rẹ ti wọn fi han
Nipa ti ọmu Comfort ti gbogbo aye n wo lori ayelujara bayii, Amofin Adedayo so pe bi awọn to fi han ko ba le dahun awọn ibeere to yẹ, obinrin naa le pe wọn lẹjọ lori ihoho rẹ tan han.
O ni o le sọ pe ipá ti wọn fi gbe oun lo mu ọmu fo jade bẹẹ, ti iyi obinrin oun si di nnkan ti gbogbo aye n ri.
Ṣé àìwọ kọ́mú rẹ̀ kó tóó jàde níle lòdì sófin?
Rara.
Amofin Festus Adedayo ṣalaye pe ai wọ kọmu jade Comfort ko lodi labẹ ofin.
O ni ohun ti awọn eeyan kan le ṣo ni pe ko mura bo ṣe tọ ko too jade nile, to fi di pe ọmu n fo yọ labẹ aṣọ.
Ṣugbọn ai wọ kọmu obinrin ko tumọ si lilu ofin kankan bi Amofin Adedayo ṣe sọ.
Fidio ihoho to gba ori ayelujara kan naa ko tọna rara- Minisita irinajo ofurufu
Amofin agba to tun jẹ minisita fun irinaj ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo, ti koro oju si fidio to n ṣafihan ọmu Arabinrin Comfort.
Ninu atẹjade kan ti Keyamo fi sita lọjọ Aje ọsẹ yii lo ti ni o lodi sofin gbaa bi ileeṣẹ Ibom ṣe ya fidio naa ti wọn si tun ju u sori afẹfẹ.
" Yiyẹ adehun to wa fun aabo eeyan ati imura ọmọluabi leyi. Bo ti wu ki arinrinajo naa tapa sofin to, ko sẹni to lẹtọọ lati ya fidio rẹ ko si tun pin aworan ti ko ba oju mu bẹẹ sita''
Bẹẹ ni Keyamo wi.
O ni oṣiṣẹ to ṣe eyi yoo foju wina ofin.
Bakan naa ni Peter Obi, ondije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ni 2023, sọ pe ofin to mu ẹru ko mu ọmọ lo n ṣẹlẹ ninu ọrọ yii.
Obi ni ki lo de ti won gbe Comfort ju si atimọle, ti wọn si sọ Wasiu Ayinde di aṣẹmalu, ẹran ọba.
Kí ni Comfort ṣe gan-an?
Gẹgẹ bi alaye ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu Ibom Air, ohun to waye laaarin oṣiṣẹ baaluu naa ati Arabinrin Comfort Emmanson ni pe ni kete ti awọn gbera kuro ni Uyo ni oṣiṣẹ baaluu kan si pe ki Comfort tẹle ofin ati ilana to wa ninu baaluu to si kọja jalẹ, titi Ọga agba to n lewaju baaluu fi kede.
Ileeṣẹ naa ni ọrọ yii fa ariyanjiyan laaarin Arabinrin Emmason ati oṣiṣẹ baaluu ṣugbọn wọn pada petu si ọrọ naa, ti wọn si gbera kuro ni Uyo.
Ibom Air ni kete ti baaluu balẹ si ilu Eko, arabinrin Emmanson duro fun gbogbo ero lati sọkalẹ, to si kọlu oṣiṣẹ baaluu to ni ko tẹle ofin ati ilana baaluu.
"Emmanson lọ ba awọn oṣiṣẹ baaluu, to si fa irun rẹ, yọ giigi rẹ, fọ mọlẹ, to si yọ bata lati fi lu oṣiṣẹ baaluu naa.
"O ko ọpọ ifọti fun oṣiṣẹ baaluu naa, koda eeyan to igbiyanju lati da si ọrọ naa tun jẹ igbaju. Emmanson lọ gbe ohun to pa ina lati fi kọlu oṣiṣẹ baaluu."
IbomAir ni ọga agba baaluu naa ke pe awọn ẹsọ alabo, ti oṣiṣẹ baaluu si mu Emmanson balẹ ko duro ki oṣiṣẹ alabo de.
"Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu fidio lori ayelujara, arabinrin Emmanson tun kọlu awọn ẹsẹ alabo, o tun fọ oṣiṣẹ alabo ni ifọti ."
IbomAir ni kete ti wọn gbe Emmanson kuro ninu baaluu ni ajọ FAAN fa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun iwadii.
"Arabinrin Emmanson, a ti fi ofin de arabinrin yii, ko ni ni anfani lati gun baaluu wa mọ."
Ẹgbẹ́ agbejọ́rò obìnrin ilẹ̀ Africa pè fún ìdádúró àwọn òṣìṣẹ́ tó lọ́wọ́ sí ìṣẹ̀lẹ́ yìí
Ni itẹsiwaju iṣẹlẹ yii, ẹgbẹ awọn agbẹjọro obinrin ilẹ Africa (African Women Lawyers Association) (AWLA), ẹka ti ilu Eko, lorilẹede Naijiria, ti bu ẹnu atẹ lu ohun to ṣẹlẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ AWLA fi sita lọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii, eyi ti Oludari wọn, Adesola Bello, buwọ lu ni wọn ti ni iwa to lodi gbaa ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Ibom Air wu.
Atẹjade naa pe fun iwadii kikun lori iṣẹlẹ yii, wọn si beere fun awọn nnkan wọnyi laipẹ rara:
Iwadii kikun ti ko ni ọwọ ara ita ninu, bẹrẹ lati ọdọ Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA) ati National Human Rights Commission (NHRC).
Idaduro ati ibawi fun awọn oṣiṣẹ ti aje iṣẹlẹ naa ṣi mọ lori, titi digba ti abọ iwadi yoo fi jade
3) Idanilẹkọọ kikun ti wọn yoo maa tunṣe fun awọn oṣiṣẹ ni papakọ ofurufu, lori ẹtọ awọn arinrinajo ati fifi fi ọ̀wọ̀ fun ẹya obinrin/ọkunrin.
4) Fifun obinrin ti wọn kọlu ni 'gba ma binu' to yẹ, ki wọn si tọrọ aforiji lọwọ rẹ fun idaamu ti wọn ko ba a pẹlu ihoho rẹ to gbode kan.
Ẹgbẹ AWLA pe gbogbo alẹnulọrọ lati tete da si ọrọ yii, wọn lawọn ko ni i kawọ gbera lori rẹ rara.