Kókó èsì tí ìjọba àpapọ̀ sọ fún Amẹ́ríkà rèé lórí ẹ̀sùn tó fi kan Nàíjíríà pé ó ń pa ọ̀pọ̀ Kristẹni

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nitori iroyin kan to ni awọn Kristẹni ni awon agbebọn n doju ija kọ julọ ni Naijiria, ti wọn si n pa wọn, ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere lorilẹede yii ti fesi pe irọ gbuu ni iroyin naa.

Nigba to n fesi nipa iroyin ọhun, ninu eyi ti ilẹ America aabo ti salaye pe ko si aabo ni Naijiria fun awon Kristẹni, ijọba apapọ sápejuwe rẹ bii iroyin aṣini-lọna.

Wọn ni o le mu kijọba ilẹ okeere maa ri ilẹ wa bii ibi ti wọn gbọdọ bojuto, nitori iwa ipa to n koju awon Kristẹni.

Atẹjade lati ileeṣẹ ijọba apapọ naa, ti Adele agbẹnusọ wọn, Kimiebi Ebienfa, fi sita lọjọ Ẹti, ṣalaye pe igbimọ to n ri si ọrọ ilẹ Africa l'America ti fun aarẹ Donald Trump laṣẹ lati fiya jẹ Naijiria nitori ipakupa ti wọn ni wọn n pa awọn Kristẹni, to si jẹ nitori ẹsin wọn ni wọn ṣe n pa wọn.

Aṣẹ naa waye lẹyin ijokoo awọn aṣofin to waye l'Ọjọruu, nibi ti awon aṣọfin ti fi aidunnu wọn han si bi wọn ṣe ni ijọba ko da aabo bo awon Kristẹni ninu awọn ikọlu to n waye.

Abọ iwadii ajọ kan, Observatory for Religious Freedom in Africa, sọ pe ida aadọrun-un (90%) awon Kristẹni ti wọn n pa kaakiri agbaye lọdun 2024 jẹ ọmọ Naijiria.

Laaarin oṣu Kẹwaa ọdun 2019 ati oṣu Kẹsan-an ọdun 2023, eeyan to le ni ẹgbẹrun marundinlọgọta (55,000) ni wọn pa, bẹẹ ni awọn ẹgbẹ agbesunmọmi ji eeyan ẹgbẹrun mọkanlelogun (21,000) wọgbo lọ.

'Lóòótọ́ ni ìṣòro ààbò wà, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ló fà á'

Ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere labẹ ijọba apapọ Naijiria, ni oun gba pe loootọ ni iṣoro aabo wa lorilẹede yii, ṣugbọn ọrọ ẹsin kọ lo fa a, bẹẹ ni ki i ṣe Kristẹni nikan ni wọn n pa.

"Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ gba pe iṣoro aabo n koju orilẹede yii, o ṣe pataki lati ṣalaye pe ki i ṣe ọrọ ẹsin lo n fa a, wọn ko si doju kọ ẹlẹsin kan pato.

" Ẹ jẹ ka ranti pe ọpọ ipaniyan ati igbesunmọmi to n ṣẹlẹ lapa Ariwa, nibi ti ọpọ eeyan ti jẹ Musulumi ko doju kọ ẹlẹsin kan. Iroyin yoowu to ba n tọka ohun ti ko ṣẹlẹ wulẹ fẹẹ ṣi awọn eeyan lọna ni."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

O ṣalaye pe ilẹ elede ati ẹsin to pọ ni Naijiria, bẹẹ si ni ijọba ko sinmi ninu iyanju rẹ lati kapa awọn to n da omi alaafia ilu ru.

Atẹjade naa sọ pe titi to fi mọ iṣoro awọn daran-daran ati awọn agbẹ to sabaa maa n waye ni ijọba Bola Tinubu n moju to.

Won ṣalaye pe ọpọ aṣeyọri ni awọn ṣọja n ṣe ninu igbẹ lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi.

" Fun idi eyi, a rọ awọn ileeṣẹ ilẹ okeere lati maa wadii ohun gbogbo daju ki wọn too maa sọ awon ọrọ to le da ipayinkeke silẹ ni Naijiria''

Bakan naa ni wọn rọ awon ileeṣẹ iroyin lati mọ iru ohun ti wọn yoo gbe jade.

Wọn ni ki wọn ma ṣe lọwọ si iroyin ofege ti ki i ṣe otitọ, to si le da wahala silẹ.

Atẹjade naa rọ awon alẹnulọrọ gbogbo, ileeṣẹ ati ajọ kaakiri, lati wadii ohun gbogbo finni-finni ki wọn too maa pin in kaye.

Orilẹede to faaye gba ọpọ ede, eeyan ati ìṣe ni Naijiria, ijọba apapọ loun ko ni i faaye silẹ fun ede aiyede lati da iṣọkan awọn eeyan ibẹ ru.