Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje UEFA Champions League tó gbéra sọ lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid lo gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ni saa to kọja lẹyin ti wọn gba aṣọ lara ẹgbẹ agbabọọlu Dortmund ni paapa iṣere Wembley.
Bi idije mii ṣe n bẹrẹ lonii, ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ni wọn tọka si awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn gbagbọ pe wọn yoo gba ife yii ni saa tuntun.
Ilana tuntun fun idije UEFA
Bẹrẹ lati saa yii 2024/2025 lọ, ikọ agbabọọlu mẹrindinlogoji ni yoo maa kopa.
Eyi tumọ si pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu yoo ni ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ ni ipin wọn (group stage.)
Ni saa tuntun, ẹgbẹ agbabọọlu kan ko ni maa koju ẹgbẹ agbabọọlu mẹta mii nigba meji ọtọọtọ mọ (home and away), amọ wọn yoo maa koju ẹgbẹ agbabọọlu mẹjọ ọtọtọ.
Lati pin awọn ti wọn yoo dojukọ, UEFA yoo kọkọ pin awọn ikọ ni mẹrin-mẹrin, ti wọn yoo si koju ẹgbẹ agbabọọlu meji ni 'home and away.’
Igbesẹ yii yoo fun awọn ikọ agbabọọlu laaye lati gbena woju oniruru ẹgbẹ agbabọọlu.
Yoo tun fun awọn ololufẹ bọọlu ni anfaani lati wo ifẹsẹwọnsẹ awọn ikọ to lagbara julọ ni ibẹrẹ idije naa.
Esi idije kọọkan ni yoo sọ ipo ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu yoo wa lori tabili.
Yatọ si awọn atunṣe tuntun yii, awọn atunṣe tuntun mii lo tun wa nipa bi wọn yoo ṣe maa yọ ọwọ awọn ẹgbẹ agbagbọọlu ti ko dangajia lawo idije naa ni gbogbo saa tuntun.
Ninu atẹjade kan lori ikanni ayelujara UEFA, o ni irufẹ nnkankan naa ni yoo waye si idije Europa League ati Europa Conference League.
UEFA sọ pe anfaani ti awọn atunto yii yoo ṣe ni pe yoo jẹ ki awọn ololufẹ bọọlu wo ifẹsẹwọnṣe to pọ daadaa.
Ati pe yoo si tun fun wọn lanfani lati wo ifẹsẹwọnsẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu to dangajia ninu idije naa.
Bawo ni ìfẹsẹwọnsẹ ipele akọkọ yoo se waye?
- Juventus vs PSV Eindhoven
- Young boys vs Aston Villa
- AC Milan vs Liverpool
- Bayern Munich vs Dinamo Zagreb
- Real Madrid vs Stuttgart
- Lille vs Sporting CP
To ba di ọla, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 ni yoo kan
- Bologna vs Shakhtar Donetsk
- Sparta Prague vs RB Sai burg
- Celtic vs Slovan Bratislava
- Club Brugge vs Borussia Dortmund
- Man City vs Inter
- PSG vs Girona















