You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn kọlu Ṣọ́ọ̀ṣì, Sínágọ́gù, èèyàn mọ́kàndínlógún jáde láyé
Kò dín ní aráàlú àti ọlọ́pàá mọ́kàndínlógún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àwọn kan lọ ṣe ìkọlù sí àwọn àgọ́ ọlọ́pàá àti ṣọ́ọ̀ṣì ní Degastan ní ẹkùn North Caucasus Russia.
Àwọn agbébọn mẹ́fà ló tún pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù náà.
Àwọn èèyàn tó farapa tó ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn lé ní mẹ́rìndínlógún.
Wọ́n ti kéde ọjọ́ mẹ́ta láti fi kẹ́dùn ní Dagestan, ẹkùn gúúsù Russia, ìlú tí àwọn mùsùlùmí pọ̀ sí jùlọ.
Ìkọlù náà tó wáyé jùlọ ní ìlú Derbent àti Makhachkala jẹ́ èyí tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe, tí wọ́n sì pa àlùfáà ìjọ kan níbi ìkọlù ọ̀hún.
Olórí ilẹ̀ Olómìnira Dagestan , Sergei Melikov ní àlùfáà ìjọ tí wọ́n pa náà ni Nikolai Kotelnikov tó ti wà ní Derbent fún ogójì ọdún sẹ́yìn.
Awọn fídíò tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn èèyàn kan tí wọ́n wọ aṣọ dúdú ṣe ń yìnbọn lu ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá kí ọkọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì tó dé síbẹ̀.
Ní Derbent – ìlú tí àwọn àgbà Júù pọ̀ sí – àwọn agbébọn ṣèkọlù sí sínágọ́gù àti ṣọ́ọ́ṣì kan, tí wọ́n sì tún dáná sún wọn.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí táwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam máa ṣe ìkọlù sí Dagestan.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kò ì tíì fìdí àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà múlẹ̀, àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn Russia ní àwọn ọmọ olórí ẹkùn Sergokalinsky, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Makhachkala méjì, Magomed Omarov, Osman àti Adil ló wà lára àwọn agbébọn tó ṣe ìkọlù náà.
Àwọn ọlọ́pàá ti fi Omarov sí àhámọ́.
Ẹ̀wẹ̀, nínú fídíò kan lórí Telegram, olóri ẹkùn náà, Sergei Melikov ní Ukraine lọ́wọ́ nínú ìkọlù ọ̀hún àti pé Dagestan náà ti dá sí ogun tí Russia ń gbé ti Ukraine báyìí.
Ó ní àwọn iléeṣẹ́ tó wà nídìí ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí àti àwọn nǹkan tí wọ́n ń fẹ́ yé àwọn.
Olórí ikọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Russian State Duma, Lenoid Slutsky náà gba òun tí Melikov gbọ́, ó ní ṣíṣe ìkọlù sí Dagestan àti jíju àdó olóró tó pa èèyàn mẹ́ran sí Sevastopool tí àwọn ọmọ Russia pọ̀ sí kò lè ṣàdédé wáyé lásìkò kan náà.
Slutsky ní òun gbàgbọ́ pé ìkọlù náà lọ́wọ́ àwọn ilẹ̀ òkèrè nínú láti dá ìbẹ̀rù, ìpayà àti pín àwọn èèyàn Russia ni.
Àmọ́ àgbà ọmọ orílẹ̀ èdè Russia kan, Dmitru Rogozin ṣèkìlọ̀ pé tí wọ́n bá ń di ẹ̀bi gbogbo ìkọlù tó ń wáyé ru Ukraine àti Nato, ó ṣeéṣe kó kó ìyọnu bá àwọn.
Ìkọlù sí gbọ̀gán ìlú Crocus lẹ́gbẹ̀ẹ́ Moscow nínú oṣù Kẹta ṣekúpa èèyàn 147 ni Russia di ẹ̀bi ìkọlù náà ru Ukraine àtàwọn ilẹ̀ òkèrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ẹ̀sìn Islam kan ní àwọn làwọn wà nídìí ìkọlù náà.
Agbẹnusọ Kremlin, Dmitry Peskov ní ààrẹ Vladimir Putin ti bá àwọn èèyàn ró pàdánù ẹ̀mí wọn ní Crimea àti Dagestan kẹ́dùn.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn Russia lọ́jọ́ Ajé ní ìkọlù tó ń wáyé náà ti wá sópin
Láàárín ọdún 2007 àti 2017, ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Islam tí orúkọ wọn ń jẹ́ Caucasus Emirate, kí wọ́n tó pe ara wọn ní Islamic Emirate of the Caucasus ṣe ìkọlù sí Dagestan àtàwọn ìlú tó yi ká bíi Russian Republics of Chechnya, Ingushetia àti Kabardino-Balkaria.
Lẹ́yìn ìkọlù sí Crocus City Hall ní Moscow, Ààrẹ Vladimir Putin tẹmpẹlẹmọ pé àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam kò lè máa ṣe ìkọlù sáwọn nítorí àwọn ń fààyè gba gbogbo ẹ̀sìn àti ẹ̀yà, tí àwọn sì ń ṣe dédé pẹ̀lú gbogbo ẹ̀sìn àti ẹ̀yà.
Àmọ́ ní nǹkan bíi oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ni ẹ̀ṣọ́ ààbò Russia ní àwọn dabarú bí ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Islam tó fẹ́ ṣe ìkọlù sí sínágọ́gù Moscow.