Ta ló rápálá wọ ìnú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke tó fi ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀?

Awọn onijibiti ori ayelujara kan ti gba akoso ọkan lara awọn ẹrọ ibanisọrọ gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Rasheed lo sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun.

Agbẹnusọ fun gomina Adeleke rọ araalu lati dẹyẹsi ipe kankan to ba kan siwọn lati ori nọmba ibanisọrọ +2348033657555.

Atẹjade naa ni wọn “ti n gbe igbesẹ to jọju lati yanju ọr naa”

O ni awọn ileeṣẹ alaabo ti n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa ati lati daabo to yẹ bo awọn nọmba ibanisọrọ gomina naa.

Tẹjade naa ko sọ ni pato ohun ti awọn onijibiti ori ayelujara naa ti da lara pẹlu nọmba gomina Adeleke amọṣa ohun ti wọn fi kọ atẹjade naa fihan pe ohun to ti da awọn to sun mọ gomina naa ati iṣejọba rẹ si hilahilo ni iṣẹlẹ naa.

Iṣẹlẹ gbigba akoso ẹrọ ibanisọrọ ẹni lọna aitọ kii ṣe tuntun lorilẹede Naijiria.

Ni ibẹrẹ ọdun 2024 ni iroyin jade pe awọn onijibiti ori ayelujara kan ti yọ wọ inu foonu sẹnetọ nigbakan ri, Tokunbọ Afikuyọmi to si padadu ẹgbẹlẹgbẹ owo nipasẹ rẹ.