You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn pásítọ̀ Nàìjíríà tó wáàsù níbi ètò ìbúrawọlé Donald Trump
- Author, Catherine Heathwood
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Awọn gbajugbaja pasitọ meji lati orilẹede Naijiria wa nibi ayẹyẹ iburawọle fun Aarẹ Donald Trump lọjọ Aje.
Pasitọ William F. Kumuyi ni ko le yooju sibi eto iburawọle naa lẹyin ti wọn ransẹ pe nitori bi kurukuru oju ọjọ se .
Ṣugbọn o lo akoko nibi akanse eto adura ti wọn se fun Aarẹ tuntun naa pẹlu ipade pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu.
Wiwa Kumuyi si eto iburawọle naa lo ya ọpọ lẹnu. Bo ti lẹ jẹ pe Trump fi itan balẹ pẹlu bi o se ransẹ pe awọn olori lagbaye lati China, Italy ati Argentina, ṣugbọn ko si ẹnikẹni to wa lati ilẹ Adulawọ.
Yatọ si Kumuyi, Trump tun ransẹ pe akọrin ẹmi oniwaasu, Nathaniel Bassey lati fi orin adura bọ wọn ni owurọ ọjọ Aje.
Ta ni William Kumuyi?
Ọjọgbọn fun iṣiro tẹlẹ, Pasitọ William F. Kumuyi ni oludasilẹ ile ijọsin Deeper Life lorilẹede Naijiria ati lagbaye.
Ninu atẹjade kan, Ajọ Global Crusade ni ile ijọsin Deeper Life lo wa ni ipo kẹta ile ijọsin lagbaye, to si jẹ pe o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to wa ni ile ijọsin ni oṣoṣu.
Nigba to de si ilu Amẹrika, Kumuyi gbe soju opo ayelujara pe o pade awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Amẹrika.
Ni ọjọ Aiku, o se adura nibi eto Inauguration Praise & Prayer convocation, ti pasitọ Amẹrika, Jim Garlow ati Tony Perkins gbe kalẹ.
Ta ni Nathaniel Bassey?
Yatọ si pe o jẹ akọrin ẹmi to wa lati orilẹede Naijiria, Nathaniel Bassey jẹ pasitọ, onkọrin, onfọnfere to wa lati ipinlẹ Akwa Ibom ni guusu Naijiria.
O di ilu mọka pẹlu orin rẹ ati isọji rẹ lori ayelujara, to si le ni milọnu mẹrin eeyan to n tẹle lori ayelujara.
O ni oun bẹrẹ lati ma kọrin lori ayelujara ni ọdun 2017 to ni ajọsepọ pẹlu awọn Kristẹni lagbaye.
Bo ti lẹ jẹ pe, Bassey pe ara rẹ ni Pasitọ, ọpọ eeyan mọ si akọrin ẹmi. O jẹ pasitọ ọdọ nile ijọsin Redeemed Christain Church of God niluu Eko.
Bassey ni olorin to wa lati ilẹ Afrika lati kọrin nibi eto kan ti wọn fi da Trump lọla.
Ki lo de ti wọn fi wa nibẹ?
Trump gbajumọ laarin awọn oludibo Kristẹni, to si ṣe ileri pe wọn yoo di rọ opo ati igbagbọ ẹsin naa.
Dion Forster, Ọjọgbọn ni fasiti Amsterdam ni Trump ati Kumuyi yoo jere latari bi Kumuyi se wa si ibi eto iburawọle naa.
O ni Kumuyi le sọ bayii pe "Ọrẹ ni mo jẹ fun eeyan to lagbara ju lagbaye."
Fun ipa rẹ, Trump ati ikọ rẹ le lo agbara Kumuyi lati ri agbara gba ni ilẹ Afrika.
Caleb Okereke, oludasilẹ Minority Africa ni o gba pe awọn pasitọ bii Kumuyi ati Bassey le ran Trump lọwọ ni ilẹ Afrika pupọ.