You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akọ tó di abo lóyún, bímọ fún ọkọ rẹ̀ tíí ṣe abo tó di akọ
Àwòrán àwọn tọkọtaya kan tó jẹ́ wí pé wọ́n pa isẹda ara àwọn dà kúrò sí bí wọ́n ṣe bí wọn, ti ń gba orí ayélujára.
Ziyal Paval, ẹni ọdún mọ́kànlélógún àti olólùfẹ́ rẹ̀, Zahad, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ló ṣe ìdádúró ìgbésẹ̀ pípáàrọ̀ ara wọn, láti bí ọmọ.
Ní ìpínlẹ̀ Kerala ni àwọn méjéèjì ń gbé ní orílẹ̀ èdè India.
Paval tó jẹ́ ọkùnrin, nígbà tí wọ́n bi ṣùgbọ́n tó ti ń pààrọ̀ ara rẹ̀ sí obìnrin báyìí, ní ó ti máa ń wu òun láti jẹ́ òbí.
Tí Zahad tó jẹ́ ọkunrin nígbà tí wọ́n bi, tó sì ti ń pààrọ̀ ara rẹ̀ sí obìnrin báyìí, ló lóyún, tí wọn sì ti kéde pé àwọn ti bí ọmọ bayii.
"A ko gbọ ri pe awọn eeyan to paarọ isẹda ara wọn di obi ni India"
Ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Keji ni Zahad bímọ tí wọ́n sì sọ fún BBC pé àláfíà ni àwọn méjéèjì wà àmọ́ wọn kò sọ bóyá akọ tàbí abo ni wọ́n bí.
Paval ṣàlàyé pé tí ọmọ àwọn bá ti pé oṣù méjì ni Zahad ma padà sẹ́nu iṣẹ́ tí òun yóò sì máa tọ́jú ọmọ lọ, tí òun náà yóò sì gbájúmọ́ iṣẹ́ ijó jíjó òun síi.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti ń kí àwọn méjéèjì kú oríire lórí ẹ̀rọ ayélujára pe wọn ku ayọ ọmọ tuntun naa.
Lábẹ́ àwọn àwòrán tí Paval fi sórí Instagram rẹ̀ ni òṣèré S Negha tí òun náà pàrọ̀ ara rẹ̀, kọ ọ̀rọ̀ sí pé àwọn tó bá pàrọ̀ ara wọn náà nílò láti ní ẹbí.
Paval àti Zahad ní àwọn ènìyàn tó pàrọ̀ ara wọn, tí wọ́n wá bí ọmọ ti wọn gangan kéré jọjọ ní India.
O ni nítorí náà, àwọn kò gbọ́ rí pe kí ènìyàn bí irú àwọn kankan pe ara wọn ní òbí.
Àwọn ènìyàn tó pa ara wọn dà kúrò sí bí wọ́n ṣe bí wọn, ni ìgbàgbọ́ wà wí pé wọ́n tó mílíọ̀nù méjì tó wà ní India.
àmọ́ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ kan sọ wí pé iye wọn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ní ọdún 2014 ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní India dájọ́ pé àwọn ènìyàn tó pààrọ ara wọn náà yálà akọ tó paradà sí abo tàbí abo tó bá paradà sábo ní ẹ̀tọ́ kan náà pẹ̀lú àwọn ènìyàn yòókù láwùjọ.
Àmọ́ síbẹ̀ àwọn ènìyàn ṣì máa ń fi ojú àbùkù wò wọ́n tí wọn kìí sì ní àǹfàní sí ètò ẹ̀kọ́, ìlera àti àwọn nǹkan mìíràn láwùjọ.
Ọ̀dọ́ àwọn tó pàrọ̀ ara wọn ni mo ti kọ́ ijó jíjó nígbà tí àwọn òbí mi tó jẹ́ mùsùlùmí kò fàyè gbà mí - Paval
Nígbà tí Paval àti Zahad pàdé ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, àwọn méjéèjì ni wọ́n ń kojkú ìṣòro lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn nítorí irúfẹ́ ìgbé ayé tí wọ́n fẹ́ gbé.
Paval ní ìdílé mùsùlùmí tí kò fi ààyè gba ijó jíjó ni òun ti wá dèbí wí pé àwọn òbí òun máa ń gé irun òun láti dènà láti kópa nínú ijó jíjó.
Ó ní òun sá kúrò nílé nígbà tí òun lọ kópa nínú ayẹyẹ àwọn ọ̀dọ́ tí òun kò sì bojú wẹ̀yìn mọ́.
Ó ṣàlàyé pé lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tó pààrọ̀ ara wọn ni òun ti kọ́ ijó jíjó tí òun náà si ti ń kọ àwọn ènìyàn báyìí ní ẹkùn Kozhikode.
Zahad ní tirẹ̀ tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣirò owó wá láti ìdílé kristẹni ní agbègbè Thiruvananthapuram tó sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtajà kan báyìí.
Nígbà tó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé òun fẹ́ pa ara òun dà ní ó kúrò nílé àmọ́ òbí rẹ̀ ti gba àwọn tọkọtaya náà tọwọ́ tẹsẹ̀ báyìí.
Ọdún kan àbọ̀ sẹ́yìn la pinnu láti bímọ
Paval sọ fún BBC pé ní nǹkan bí i ọdún kan àbọ̀ sẹ́yìn nígbà tí àwọn ti ń ṣiṣẹ́ abẹ láti yí ara àwọn padà ni àwọn ti pinnu láti bímọ ná kí àwọn tó tẹ̀síwájú.
“Wọn ò tíì yọ ilé ọmọ àti àwọn ẹ̀yà tó le fi bímọ lára Zahad tí dókítà sì gbàwá nímọ̀ràn láti bímọ ná ka tó ṣe bẹ́ẹ̀.”
Dókítà Mahesh ní kété tí wọ́n bá ti bímọ tán ni wọ́n le tẹ̀síwájú pẹ̀lú àyípadà ara tí wọ́n ń ṣe lọ.
Àwọn tọkọtaya náà ní kété tí àwọn bá ti bímọ tán ni àwọn máa gbájúmọ́ iṣẹ́ àwọn nítorí à ti lè jẹun.