Ara Nnamdi Kanu le láti máa jẹ́jọ́ - Àbọ̀ ìwádìí àwọn dókítà sọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti kọ̀ láti gba ìpè olórí ikọ̀ Indigenous People of Biafra (IPOB) láti lọ gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ti ìlú Abuja.

Adájọ́ James Omotosho tó da ìpè náà nù lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 sọ pé àbọ̀ ìwádìí àwọn dókítà lórí àyẹ̀wò ti wọ́n ṣe fún Nnamdi Kanu fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ara Nnamdi Kanu le láti jẹ́jọ́.

Gẹ́gẹ́ àbọ̀ ìwádìí tí ẹgbẹ́ àwọn dókítà ilẹ̀ Nàìjíríà, NMA ṣe, wọ́n ní ìwádìí náà fi hàn pé àìsàn tó ń ṣe Kanu kìí ṣe èyí tó le la ẹ̀mí lọ àti pé ilé ìwòsàn tó wà ní ọgbà àwọn DSS tí Nnamdi Kanu wà le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Níbi ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu tó wáyé lọ́jọ́bọ̀, agbẹjọ́rò fún ìjọba àpapọ̀, Adegboyega Awomolo sọ pé ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá ni àwọn ti gba ìjábọ̀ àwọn dókítà, tí wọ́n sì ti fi le àwọn agbẹjọ́rò Kanu lọ́wọ́.

Agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu, Kanu Agabi sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn gba ìjábọ̀ náà, tí àwọn sì ti kà á.

Adájọ́ Omotosho ní àwọn máa tẹ̀lé èsì àwọn dókítà náà, tí àwọn sì gbà pé ìlera rẹ̀ le láti máa jẹ́jọ́ lọ.

Kanu Agabi bẹ ilé ẹjọ́ láti fún àwọn ní ọjọ́ kan láti fún Nnamdi Kanu láàye wá sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó gbáradì fún wíwí tẹnu rẹ̀ nílé ẹjọ́.

Ó ní ẹ̀rù máa ń bá àwọn láti sọ̀rọ̀ ní ọgbà DSS nítorí kò sí àṣírí bíbò níbẹ̀ àti pé àwọn DSS máa ń tẹ́tí sí nǹkan tí àwọn bá ń sọ.

Adájọ́ gbà sí wọn lẹ́nu, tó sì fún wọn ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 láàárín aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ sí aago kan ọ̀sán kí Nnamdi Kanu àti agbẹjọ́rò rẹ̀ fi sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́.

Lẹ́yìn náà ló mú ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹwàá láti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu, tí ìgbẹ́jọ́ náà yóò sì wáyé fún ọjọ́ méje – 23, 27, 28, 29 àti 30 oṣù Kẹwàá.

Àbọ̀ ìwádìí NMA

Ẹgbẹ́ àwọn dókítà Nàìjíríà, NMA tí ilé ẹjọ́ pa láṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò ìlera Nnamdi Kanu, sọ pé ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni àwọn ti ṣe àyẹ̀wò náà.

Wọ́n ní àyẹ̀wò tí àwọn ṣe fún Nnamdi Kanu ṣàfihàn pé ó ní àwọn àìsàn wọ̀nyí:

  • Ẹ̀jẹ̀ rúru
  • Refractive Error/Presbyopia
  • Àìsàn ojú gbígbẹ
  • Inflamed Stage 2 Nasal Pterygium right eye
  • Àìsàn kíndìnrín tó wà ní ipele kẹta
  • Chronic kidney disease stage 3A secondary to hypertension/Benign Prostatic Enlargement (BPE)
  • Obstructive Nephropathy Secondary to Benign Prostatic Enlargement (BPE)
  • Cervical Spondyloradiculopathy
  • Bilateral Axillary Lipoma
  • Chronic Rhinosinusitis pẹ̀lú septal deviation

Nínú ìjábọ̀ wọn, wọ́n ní kí Nnamdi Kanu máa lo àwọn òògùn kan àti pé kó ṣe ìdádúró àwọn òògùn kan tó ń lò tẹ́lẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ni kó máa ṣe àwọn nǹkan míì bíi:

  • Functional endoscopic sinus surgery (FESS) + Septoplasty àti Turbinoplasty
  • Excision biopsy of axillary lipoma
  • Cytoscopy àti Uroflowmetry
  • Cervical spine MRI
  • Relieve of bladder outlet obstruction

Ní ìkádìí, wọ́n ní àbọ̀ ìwádìí àwọn kò ṣàfihàn pé ó ní àìsàn tó le ṣe àkóbá fún ẹ̀mí rẹ̀ àti pé ó le máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbẹ́jọ́.

Wọ́n ní tó bá ń lo àwọn oògùn tí àwọn kọ fun yóò mú kí ìlera jí pépé ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí ilé ìwòsàn tó wà ní ọgbà àwọn DSS, wọ́n ní ilé ìwòsàn náà ní àwọn ohun èèlò tó yẹ láti fi tọ́jú Nnamdi Kanu ṣùgbọ́n wọ́n ní ilé ìwòsàn náà máa nílò àwọn ohun èlò àtàwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ síi láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n kọ sínú ìjábọ̀ náà.

Ìjábọ̀ náà ni àwọn ìgbìmọ̀ mẹ́jọ tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó ṣe ìwádìí náà buwọ́lù nígbà tí Bala Mohammad Audu àti Benjamin Egbo tí wọ́n jẹ́ ààrẹ àti akọ̀wé NMA sì buwọ́lu ìjábọ̀ pé ara Nnamdi Kanu le láti jẹ́jọ́.