You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
CBN wọ́gilé ìwé ẹ̀rí iléeṣé bánkì alábọ́dé 132
- Author, Olumide Owaduge
- Role, Akọroyin BBC
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti wọgile iwe aṣẹ awọn ile ifowopamọ alabọde méjìlélàádóje (132).
Lara awọn ile ifowopamọ naa ni Atlas Microfinance Bank; Bluewhales Microfinance Bank; Everest Microfinance Bank; Mainsail Microfinance Bank; Nopov Microfinance Bank; Ohon Microfinance Bank; Premium Microfinance Bank ati Statesman Microfinance Bank.
Awọn mii ti ọrọ yii tun kan ni Manny Microfinance Bank; Reality Microfinance Bank; Osina Microfinance Bank; Zikado Microfinance Bank; Taraba Microfinance Bank, Ndiagu Microfinance Bank, atawọn mii.
CBN tun gba iwe aṣẹ awọn ileeṣẹ mii to n ri si eto iṣuna bi HHL Invest & Trust Limited, TFS Finance Limited ati Treasures & Trust Limited.
Yatọ si awọn wọnyii, ijọba tun gba iwe Eri Resort Savings & Loans, Safetrust Mortgage Bank, Adamawa Savings & Loans ati Kogi Savings & Loans.
Ninu atẹjade kan ti ijọba apapọ fi lede, o ni awọn ileeṣẹ naa ti kuna lati ṣiṣẹ gẹgẹ bii iwe ẹri ti wọn fun wọn fun oṣu mẹfa o le.
Atẹjade naa ti gomina CBN, Godwin Emefiele buwọlu sọ pe awọn ileeṣẹ ọhun kuna lati tẹle ilana ofin to rọ mọ iwe ẹri iṣẹ ti wọn gba.
O ni “Nitori naa, emi, Godwin Ifeanyi Emefiele, CON, ti mo jẹ gomina bank apapọ Naijiria, ninu ojuṣe mi gẹgẹ bii agbara ti ofin CBN ‘section 12 of BOFIA 2020, Act No.5.’ fun mi.”
“Mo wọgile iwe ẹri iṣẹ awọn ile ifowopamọ alabọde wọnyii, to fi mọ awọn ileeṣẹ to n ri si eto iṣuna.”