Àwọn àǹfàání àti èèwọ̀ tó rọ̀ mọ́ ìlù Gángan ní ilẹ̀ Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilu Gangan nilẹ Yoruba jẹ ohun pataki, ko fẹ si ilu kan nilẹ Yoruba ti ko fẹ ilu yii.

Ọpọ awọn onilu ṣapejuwe ilu Gangan gẹgẹ bii ‘oku ewurẹ to n fọhun bi eeyan’.

Yatọ si pe wọn gbe ilu lọ si ode ere fun idanilaraya, ọpọ awọn nnkan ni wọn n fi ilu se nilẹ Yoruba.

Gbogbo ọmọ to ba ti ile onilu jade ni wọn ma n pe ni Ayan.

Lasiko igba aye Alaafin Lamidi Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo to waja laipẹ yii, ati lasiko ayẹyẹ ilu niluu Abeokuta - pataki ni ilu jẹ fun Ilẹ Yoruba nitori ko si ibi kibi ti wọn ti n lu ilu ti kii fọhun.

Ilu jẹ ohun pataki ni ile awọn ọba nla nla ni ilẹ Yoruba, ti o si tun wọpọ ni ile awọn eeyan olokiki.

Alaafin Adeyemi sọ lọdun 2017 pe, ilu ma n jẹ ki oun ranti ẹjẹ ti oun da fun awọn eeyan Oyo ni araarọ lojumọ.;

“Ni aago marun un laarọ ni ilu yoo ji ọba, ti yoo si ma sọ fun nipa ẹjẹ to jẹ fun awọn eeyan ati awọn baba nla rẹ.

“Awọn onilu yoo kọkọ pe mi laarọ ki wọn to pe awọn baba mi to jẹ alaafin.”

Yatọ si fifi ilu ki ọba alade, ọpọ nnkan ti wọn ma n fi ilu ṣe ni ilẹ Yoruba ni bii ka fi pa owe, ka fi kilọ fun eeyan, ka fi da ni laraya, ilu ma n lọ si ogun.

Bakan naa lo ṣoro ki ọba alade lọ si ode lai si onilu ti yoo tẹle wọn.

Oriṣa Ayan-Agalu

Ayan-Agalu jẹ oriṣa ilu gangan, ti ọpọ awọn onilu si ma n bọ ọ ni igbakugba to ba wu wọn.

Itan ni, Ayan-Agalu ni onilu akọkọ to lu ilu to n sọrọ.

Ayanyemi Atokowagbowonile ba BBC Yoruba sọrọ lori bi awọn onilu se ma n bọ oriṣa Ayan-Agalu.

O ni bii pe wọn fẹ se oku agba ni wọn se ma se oro fun ilu nilẹ Yoruba.

“A o da aṣo funfun bo ni ori ẹni fun ọjọ marun un, ti a o si fi ekuru si lori ati gbogbo nnkan ti a fi n bọ.”

“Lẹyin naa ni a gbe ounjẹ lọ fun awọn agbalagba.”

Ki ni awọn eewọ ilu ni ilẹ Yoruba?

Gẹgẹ bi a ṣe sọ ṣaaju, pataki ni ilu jẹ nilẹ Yoruba, koda o ni oriṣa ti ọpọ idile onilu ma n bọ.

Ọkan gboogi ninu eewọ ilu ni pe wọn ko gbọdọ gbe silẹ ni igbakugba.

Ayanyemi ni eeyan to ba n lu ilu gbọdọ ma se oro rẹ ni ẹẹkan lọdun lati fi tu awọn agbaagba lọkan .

Bakan naa lo tun tọka si jijẹ aguntan, Ayanyemi ni onilu ko gbọdọ jẹ aguntan rara.

Ayanyemi tẹsiwaju pe ilu ko fẹ idọti rara, ti onilu si gbọdọ ri pe oun se itọju rẹ nitori oun lo n pese owo.

“Ti eeyan o ba se eyi, ohun ti yoo gbe jade ko jẹ ohun to yẹ ko gbe jade.

“Bi eeyan se n tọju ọmọ ni a n tọju ilu”