You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé aṣòfin àgbà ṣí ọ́fíìsì Sẹ́nẹ́tọ̀ Natasha padà lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé e tì pa fóṣù mẹ́fà
Ile aṣofin agba niluu Abuja ti ṣi ọfiisi Sẹnẹtọ Natasha Akpot-Uduaghan, to n ṣoju aaringbungbun ipinlẹ Kogi, pada lẹyin ti wọn ti wọn ni ki sẹnẹtọ naa lọ rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.
Ẹsun wi pe o tapa si ofin ile ni wọn fi kan Natasha ti wọn fi da a duro nigba naa.
Igbakeji adari eto aabo nile aṣofin, Ọgbẹni Alabi Adedeji, lo ṣi ọfiisi naa pada lanaa ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an yii, eyi ti yoo fun Natasha lanfaani lati pada sile lẹyin to ti wa ni idaduro fun oṣu mẹfa gbako.
Nigba ti o fẹ ṣi ọfiisi naa, Ọgbẹni Adedeji sọ pe ''emi Alabi Adedeji, igbakeji adari eto abo ile aṣofin agba ṣi ọfiisi Sẹnẹtọ Natasha Akpoti.''
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ninu oṣu Keji ọdun 2025 ni ede aiyede ṣẹlẹ ni ile aṣofin agba Naijiria, laarin Aarẹ ile naa, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan.
Akpabio paṣẹ lasiko ti ijiroro n lọ pe, ki awọn oṣiṣẹ alaabo gbe e jade lẹyin ti obinrin naa kọ lati joko ni aaye tuntun ti wọn fun, to si sọ awọn ọrọ ibinu.
O fi ẹsun kan Akpabio pe o mọọmọ fẹ pa oun lẹnu mọ ni, to si fẹ gba anfaani ti oun ni lati da si ijiroro ile, lọwọ oun.
Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lọjọ naa, ile aṣofin fi ẹsun kan Natasha pe o tapa si awọn ilana ile naa, pẹlu bo ṣe kọ lati jokoo si aaye ti wọn fun un.
Ọrọ naa de iwaju igbimọ to n ba awọn aṣofin wi, ṣugbọn Natasha kuna lati farahan niwaju igbimọ naa.
Lẹyin rẹ ni wọn kede pe wọn ti da a duro fun oṣu mẹfa.
Ọrọ ọhun pada di ti ile ẹjọ, pẹlu bi igun mejeeji ṣe pe ẹjọ ọtọọtọ lori rẹ.
Loṣu Keje to kọja nile ẹjọ paṣẹ pe ki Natasha pada sile
Ninu oṣu Keje to kọja ni Ile ijọ giga kan niluu Abuja paṣẹ pe ki wọn da Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan, pada sẹnu iṣẹ rẹ lẹyin ti ile aṣofin naa ni ko lo rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Binta Nyako sọ pe oṣu mẹfa ti wọn ni ko lọ rọọkun nile ti pọju.
Nyako ni gẹgẹ bii abala 14(2) ofin to sọ nipa anfaani awọn aṣofin ṣe sọ, ijiya ti wọn fun aṣofin naa ko tọ ọ.
Adajọ ọhun fi kun pe ko tọ ki ẹkun idibo ti Natasha n ṣoju wa lai ni aṣoju kankan nile igbimọ aṣofin Naijiria.
Ẹwẹ, ile ẹjọ ọhun sọ pe Natasha jẹbi titapa si ofin ile ẹjọ nitori bo ṣe fi Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ṣere lasiko to bẹ ẹ loju opo Facebook rẹ nigba ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ.
Fun idi eyii, adajọ naa ni o gbọdọ san owo itanran ti iye rẹ jẹ miliọnu marun un naira fun ile ẹjọ.
Adajọ fi kun pe Natasha gbọdọ kọ iwe ẹbẹ loju opo Facebook rẹ ati ninu iwe iroyin meji ọtọọtọ to gbajumọ ni Naiiria.
O ni o gbọdọ ṣe gbogbo awọn nnkan wọnyii laarin ọjọ meje pere lẹyin idajọ naa.
Ile aṣofin agba dena mọ Natasha lati pada sile
Ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ni Natasha kọ iwe sile aṣofin wi pe oun ṣetan lati pada sẹnu iṣẹ oun lẹyin ti oṣu mẹfa ti wọn ni ko fi lọ rọọkan nile ti pe.
Amọ, awọn aṣofin yari pe awọn ko ni gba a laye lati pada sile, ayafi ti ẹjọ to wa nile ẹjọ ba pari.
Ile aṣofin sọ pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo idaduro Natasha to bẹrẹ lọjọ kẹfa oṣu Kẹta ọdun yii lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọun ba gbe idajọ rẹ kalẹ lori ọrọ naa.
Gbogbo igba ni Natasha maa n sọ wi pe nitori ẹsun iyọnilẹnu fun ibalopọ ti oun fi kan aarẹ ile, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, eyi ti ile yi danu ni wọn n fi fooro ẹmi oun.
Ile aṣofin agba sun ijokoo si ọjọ Keje oṣu Kẹwaa
Ẹwẹ, ile aṣofin agba ti sun ijokoo ile si ọjọ keje osu Kẹwaa to n bọ yii, eyi to tumọ si pe ile ko ni jokoo fun ọsẹ meji.
Akọwe ile, Kamoru Ogunlana, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu lẹta kan to fi ṣọwọ gbogbo ile.
Ọgbẹni Ogunlana rọ gbogbo aṣofin ṣakiyesi ọjọ ti ijokoo yoo bẹrẹ pada.
''Igbimọ alaṣẹ ile aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin ni ki n sọ fun gbogbo aṣofin ati araalu wi pe ijokoo ile to yẹ ko bẹrẹ tẹlẹ lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an yii ti di sisun siwaju si ọjọ keje oṣu Kẹwaa to n bọ.
Amọ, awọn igbimọ ile yoo maa ba iṣẹ wọn lọ,'' Ọgbẹni Ogunlana lo sọ bẹẹ nilu iwe to fi ṣọwọ si gbogbo ile.