Onyeka Onwenu, gbajúmọ̀ akọrin olóhùn iyọ̀ jáde láyé, ohun tí a mọ̀ nípa bó ṣe kú rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ akọrin olohun iyọ ni, Onyeka Onwenu ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrin.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, eekan akọrin miran, Charly boy to gbe iroyin iku oloogbe naa si ori oju opo ayelujara rẹ.

O ni lootọ ni pe Onyeka Onwenu ti jade laye. O ni oun gba iroyin iku rẹ latẹnu awọn to sun mọọ to si mọ nipa ohun to n ṣẹlẹ sii nigba aye rẹ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe ọ, ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ọgbọn ọjọ oṣu keje ọdun 2024 ni Onyeka Onwenu jade laye nigba to ṣubululẹ̀ lẹyin to ṣẹṣẹ kọrin tan nibi ajọyọ ọjọ ibi kan ni ilu Eko.

Iroyin naa tun sọ pe wọn gbe de ile iwosan ni agbegbe Ikoyi nilu Eko ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nibẹ lawọn dokita ti fi idi rẹ mulẹ pe ọlọjọ ti de ba a.

Amọṣa ko tii si ẹni sọ ni pato ohun gan to ṣokunfa iku rẹ nitori awọn ẹbi rẹ ko tii sọ ohunkohun lori iku rẹ.