You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni Saidi Balogun ṣe tí àwọn kan fi ń tàbùkù rẹ̀?
Lowurọ Ọjọbọ, gbajugbaja osere tiata, Saidi Balogun ni pupọ awọn eeyan loju opo ayelujara Twitter mu orukọ rẹ bọ ẹnu.
Orukọ suna lorisiri si ni wọn pe osere tiata naa lẹyin to gbe fọnran kan jade eyi to n pe fun titako bi awọn eeyan se n fẹ gba ijọba lorilẹede Naijria.
Ṣaaju ni ileesẹ DSS ti kede pe awọn oloselu kan ti n dete lati doju ijọba tiwantiwa bolẹ, ti wọn si fẹ da ijọba awarawa ru.
Saidi Balogun, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni pupọ awọn eeyan loju opo Twitter lo wa lara awọn to n fa rogbodiyan tori oun to gbe sita loju opo rẹ.
Ninu ọrọ to gbe sori ayelujara, Balogun ni eto idibo to waye lorilẹede Naijiria lọ ni laisi wahala, fun idi eyi ko si aye fun awọn oloselu to fẹ doju ijọba tiwatiwa bolẹ.
"Ijọba awarawa kii n se awade, idibo waye lai si wahala, ẹ jẹ ka fa isọkan mọra."
Ọrọ Saheed Balogun yii ni ko dun mọ awọn eeyan kan ninu loju opo ayelujara Twitter, ti wọn si bẹrẹ si maa tabuku oṣere tiata naa.
Ọpọ awọn to bu ẹnu atẹ lu ọrọ Saidi Balogun yii lo jẹ ọdọ, ti wọn si korira ẹgbẹ oṣelu APC ati aseyọri wọn ninu eto idibo to kọja.
Wo awọn osere miiran ti wọn gau lẹyin to se atilẹyin fun oloselu
Toyin Abraham
Fa ki n fa a tun waye lori ayelujara lọjọ idibo gomina ati aṣofin ipinlẹ to si gbe orukọ gbajugbaja oṣere Toyin Abraham sori bii harahara.
Ṣe ni awọn ọdọ doju ọrọ kọ oṣere obinrin naa gẹgẹ bi wọn ṣe n kọ oniruuru ọrọ ati ibeere sita ti wọn si n lẹ orukọ rẹ mọ ọ lati lee jẹ ko ri gbogbo ohun ti wọ́n n kọ nipa rẹ.
Remi Surutu
Gbajugbaja oṣere tíata, Remi Oshodi ti ọpọ mọ si Remi Surutu naaa pẹlu awọn to kọminu lori bi eniyan kan ṣe fi iku ọmọ rẹ̀ agba bu u.
Itahunsira laarin Surutu ati ẹni naa waye lori ayelujara nítori ẹgbẹ òṣelu tí oṣerebìnrin yii yàn laayo.
Macaroni
Debo Adeboye naa pẹlu osere tiata to ke siat pe awọn eeyan kan le pa ẹmi rẹ nitori pe kọ lati se atilẹyin fun oloselu kan ti ko darukọ rẹ sita
Ọpọ igba ni Macaroni fi atẹjisẹ to n gba lori pe wọn lepa ẹmi rẹ sita fun awọn alatilẹyin rẹ.
Àwọn adigunjalè ṣèkọlù sí ilé adẹ́rìínpòṣónú, Woli Agba n'Ibadan
Adẹrinpoṣonu, Ayo Ajewole, ti ọpọ mọ si Woli Agbe ti kede pe awọn adigunjale ṣe ikọlu si ileegbe rẹ to wa niluu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.
Ajewole lo kede isẹlẹ naa lori opo ayelujara rẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi o ṣe ko oun ati idile rẹ yọ ninu ewu awọn adigunjale.
Ileeṣẹ BBC kan si Woli Agba lati mọ bi isẹlẹ naa ṣe waye.
Ọkan lara osojumikuro to wa nibẹ lasiko ti isẹlẹ naa waye sọ pe ago meji oru ni awọn adigunjale naa wọle tọ wọn wa.
"Bi ago meji orun ni a gbọ iro ibọn, ti a si n gbọ ariwo ni ile to wa ni ẹgbẹ ọdọ wa, ṣaadede ni wọn wọ ninu agbala wa.
"Ko pẹ si asiko naa ni wọn wọlẹ to wa wa, ti wọn si gba awọn dukia.
Eeyan to ba BBC Yoruba sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ka da orukọ rẹ ṣalaye pe wọn ko ṣe ẹnikẹni leṣe rara ati pe kete ti wọn gba awọn dukia naa, ni wọn jade."