Ohun tí a mọ̀ nípa afurasí tọ́wọ́ aráàlù tẹ̀ fẹ́sùn pé ó fẹ́ jí ọmọ gbé ní Ilorin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti ní ọwọ́ ti tẹ arákùnrin kan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fẹ́ jí ọmọ gbé ní agbègbè Sobi, Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ni fídíò kan gba orí ìkànnì Facebook níbi tí àwọn kan ti ń bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fẹ́ jí ọmọ gbé.

Ohun tí wọ́n kọ sábẹ́ fídíò náà ni pé "ọ̀kan lára àwọn tó ń da Ilorin láàmú rèé, láti ìpínlẹ̀ Osun ni ẹni náà ti wá.

Ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé ó fẹ́ gbìyànyàjú láti jí àwọn ọmọdé gbé ní agbègbè Orelope ní Sobi, àwọn ará agbègbè náà àtàwọn ọlọ́pàá ti ń dá sí ọ̀rọ̀ náà."

'Mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni wọ́n máa ń fún mi lórí ọmọ kọ̀ọ̀kan'

Nínú fídíò náà ni àwọn èèyàn kan ti ń bèèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà tó pe ara rẹ̀ ní Pedro pé kí ló wá ṣe ní agbègbè náà tó sì ń fún wọn lésì pé òun fẹ́ jí ọmọ gbé ni.

Ó ní láti ìlú Osogbo ní ìpínlẹ̀ Osun ni òun ti wá àti pé ọ̀gá àwọn tó máa ń rán àwọn níṣẹ́ náà ti gba ibiṣẹ́ lọ ní ìpínlẹ̀ míì.

Ó sọ pé kìí ṣe òun nìkan ni òun wà ní Ilorin, pé àwọn pọ̀ díẹ̀ tó sì ń ka orúkọ wọn.

Nígbà tí wọ́n bi í léèrè pé èló ni wọ́n máa ń fún wọn tó sì fèsì pé mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni òun máa ń gbà lórí ọmọ kọ̀ọ̀kan àti pé ọmọ ni òun wá wá sí àdúgbò tí òun wà náà.

Bákan náà ló fi kun pé ìgbà àkọ́kọ́ tí òun máa wá sí ìlú Ilorin nìyí.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?

Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara ní àwọn ti rí fídíò tó gba orí ayélujára náà àti pé afurasí náà ti wà ní àhámọ́ àwọn.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta sọ pé afurasí náà, tí wọn kò ì tíì mọ orúkọ rẹ̀, láwọn fijilanté àdúgbò àtàwọn ọlọ́pàá gbà lọ́wọ́ àwọn kan tí wọ́n fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún un lọ́wọ́ ara wọn fẹ̀sùn pé ó fẹ́ jí ọmọ gbé.

Ó ní nǹkan bíi aago méje alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni ọwọ́ tẹ afurasí náà tó sì ti wà ní oríkò iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara.

Ejire-Adeyemi ṣàlàyé pé afurasí náà sọ pé ìpínlẹ̀ Osun ni òun ti wá táwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti fi òótọ́ múlẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án àti láti ṣàwárí àwọn mìíràn tó bá tún lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó fi kun pé àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn afurasí náà kò ì tíì yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá láti sọ ohun tí wọ́n mọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí ó le ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá lórí ìwádìí wọn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní bí ìwádìí bá ṣe ń lọ ni àwọn yóò máa fi tó aráàlú létí.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara tún rán àwọn aráàlú létí pé òfin kò fàyè gba ṣíṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara ẹni.

Ó ní yàtọ̀ sí pé kò bá òfin mú, ó le ṣokùnfà ṣíṣi ìdájọ́ ṣe, tó sì rọ àwọn aráàlú pé tí wọ́n bá kẹ́fín ohun tí kò tọ́ ní agbègbè wọn, níṣe ni kí wọ́n fi tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní agbègbè wọn létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ó fi kun pé Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Kwara, Adekimi Ojo ní ìfarajìn sí pípèsè ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara àti láti ri pé ìdájọ́ òdodo ń wáyé ní gbogbo ìgbà.