You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ariwo sọ bí Dimeji Ajibola, adarí sinimá ṣe jáde láyé
Gbajugbaja adari ere sinima lorilẹede Naijiria, Dimeji Ajibola, ẹni to da ri ere ‘Shanty Town’ ti jade laye.
Iku Ajibola lo ti sọ ọpọ oṣere tiata sinu ironu, ti o si jẹ ohun to ba ọpọ wọn lojiji.
Gbajumọ oṣere tiata, Bolanle Ninalowo lo gbe iroyin naa sita loju opo ayelujara Instagram rẹ.
O wa ṣajejuwe oloogbe Ajibola gẹgẹ bii akọṣẹmọsẹ to yanranti lawujọ.
“Mo ni fẹ rẹ, ti mo si n ṣe idaro rẹ @dimejiajibola.
“Mo gba adura ki Ọlọrun duro ti awọn mọlẹbi ati ololufẹ rẹ. Titi a o fi pade.”
Bakan naa, oṣere tiata mii, Samuel Olatunji naa kede ipapoda oloogbe lori ayelujara.
“Onibaara mi ni Dimeji Ajibola. Iroyin nipa iku rẹ ba ni lọkan jẹ pupọ. Suure o.”
Ohun pato to ṣekupa Oloogbe naa ni a a ko le ti fidi rẹ mulẹ lọwọ lọwọ bayii.
Ta ni Dimeji Ajibola?
Itan aye Oloogbe Dimeji Bankole
Ti a ba n sọrọ nipa oludari ere sinima agbelewo lorilẹede Naijiria, ọkan gboogi ni Dimeji Ajibola jẹ laarin ọpọ.
Ọjọ Kẹdogun, Oṣu kẹrin ọdun 1980 ni wọn bi Dimeji Ajibola nipinlẹ Eko.
Lati kekere rẹ ni o ti ni ifẹ si sisọ itan.
O kawe gboye ninu sise sinima lorilẹede Amẹrika .
O ti se ọpọ iṣẹ fun ọpọ ileeṣẹ lorilẹede Naijiria, to si gba ami ẹyẹ.
Ni ọdun 2023, Dimeji Ajibola ni oludari ere sinima Shanty Town ti o jẹ ilu mọka.